JOṢUA si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si ṣí kuro ni Ṣittimu, nwọn si dé Jordani, on ati gbogbo awọn ọmọ Israeli; nwọn si sùn sibẹ̀ ki nwọn ki o to gòke odò. O si ṣe lẹhin ijọ́ mẹta, ni awọn olori là ãrin ibudó já; Nwọn si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Nigbati ẹnyin ba ri apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti ẹ ba si ri awọn alufa awọn ọmọ Lefi rù u, nigbana li ẹnyin o ṣí kuro ni ipò nyin, ẹnyin o si ma tọ̀ ọ lẹhin. Ṣugbọn alafo yio wà li agbedemeji ti ẹnyin tirẹ̀, to bi ìwọn ẹgba igbọnwọ: ẹ má ṣe sunmọ ọ, ki ẹnyin ki o le mọ̀ ọ̀na ti ẹnyin o gbà; nitoriti ẹnyin kò gbà ọ̀na yi rí. Joṣua si wi fun awọn enia pe, Ẹ yà ara nyin simimọ́: nitori li ọla OLUWA yio ṣe ohuniyanu lãrin nyin.
Kà Joṣ 3
Feti si Joṣ 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joṣ 3:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò