Joṣ 22:1-9

Joṣ 22:1-9 YBCV

NIGBANA ni Joṣua pè awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ṣe gbogbo eyiti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin, ẹnyin si gbọ́ ohùn mi ni gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun nyin: Ẹnyin kò fi awọn arakunrin nyin silẹ lati ọjọ́ pipọ̀ wọnyi wá titi o fi di oni, ṣugbọn ẹnyin ṣe afiyesi ìlo ofin OLUWA Ọlọrun nyin. Njẹ nisisiyi OLUWA Ọlọrun nyin ti fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: njẹ nisisiyi ẹ pada, ki ẹ si lọ sinu agọ́ nyin, ati si ilẹ-iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA ti fun nyin ni ìha keji Jordani. Kìki ki ẹ kiyesara gidigidi lati pa aṣẹ ati ofin mọ́, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin, lati fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, ati lati ma rìn ni gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀ mọ́, ati lati faramọ́ ọ, ati lati sìn i pẹlu àiya nyin gbogbo ati pẹlu ọkàn nyin gbogbo. Bẹ̃ni Joṣua sure fun wọn, o si rán wọn lọ: nwọn si lọ sinu agọ́ wọn. Njẹ fun àbọ ẹ̀ya Manasse ni Mose ti fi ilẹ-iní wọn fun ni Baṣani: ṣugbọn fun àbọ ẹ̀ya ti o kù ni Joṣua fi ilẹ-iní fun pẹlu awọn arakunrin wọn ni ìha ihin Jordani ni ìwọ-õrùn. Nigbati Joṣua si rán wọn pada lọ sinu agọ́ wọn, o sure fun wọn pẹlu, O si wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ pẹlu ọrọ̀ pipọ̀ si agọ́ nyin, ati pẹlu ohunọ̀sin pipọ̀, pẹlu fadakà, ati pẹlu wurà, ati pẹlu idẹ ati pẹlu irin, ati pẹlu aṣọ pipọ̀pipọ: ẹ bá awọn arakunrin nyin pín ikogun awọn ọtá nyin. Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse si pada, nwọn si lọ kuro lọdọ awọn ọmọ Israeli lati Ṣilo, ti mbẹ ni ilẹ Kenaani, lati lọ si ilẹ Gileadi, si ilẹ iní wọn, eyiti nwọn ti gbà, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA lati ọwọ́ Mose wá.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joṣ 22:1-9

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa