Gbogbo ilu awọn ọmọ Lefi ti mbẹ lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli jẹ́ ilu mejidilãdọta pẹlu àgbegbe wọn. Olukuluku ilu wọnyi li o ní àgbegbe wọn yi wọn ká: bayi ni gbogbo ilu wọnyi ri. OLUWA si fun Israeli ni gbogbo ilẹ na, ti o bura lati fi fun awọn baba wọn; nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀. OLUWA si fun wọn ni isimi yiká kiri, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o bura fun awọn baba wọn: kò si sí ọkunrin kan ninu gbogbo awọn ọtá wọn ti o duro niwaju wọn; OLUWA fi gbogbo awọn ọtá wọn lé wọn lọwọ. Ohunkohun kò tase ninu ohun rere ti OLUWA ti sọ fun ile Israeli; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ.
Kà Joṣ 21
Feti si Joṣ 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joṣ 21:41-45
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò