Joṣ 18

18
Pípín Ilẹ̀ Yòókù
1GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si pejọ ni Ṣilo, nwọn si gbé agọ́ ajọ ró nibẹ̀: a si ṣẹgun ilẹ na niwaju wọn.
2Ẹ̀ya meje si kù ninu awọn ọmọ Israeli, ti kò ti igbà ilẹ-iní wọn.
3Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin o ti lọra pẹ to lati lọ igbà ilẹ na, ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, ti fi fun nyin?
4Ẹ yàn ọkunrin mẹta fun ẹ̀ya kọkan: emi o si rán wọn, nwọn o si dide, nwọn o si là ilẹ na já, nwọn o si ṣe apejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi ilẹ-iní wọn; ki nwọn ki o si pada tọ̀ mi wá.
5Nwọn o si pín i si ọ̀na meje: Juda yio ma gbé ilẹ rẹ̀ ni gusù, ile Josefu yio si ma gbé ilẹ wọn ni ariwa.
6Ẹnyin o si ṣe apejuwe ilẹ na li ọ̀na meje, ẹnyin o si mú apejuwe tọ̀ mi wá nihin, ki emi ki o le ṣẹ́ keké rẹ̀ fun nyin nihin niwaju OLUWA Ọlọrun wa.
7Nitoriti awọn ọmọ Lefi kò ní ipín lãrin nyin; nitori iṣẹ-alufa OLUWA ni iní wọn: ati Gadi, ati Reubeni, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ti gbà ilẹ-iní wọn na ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun wọn.
8Awọn ọkunrin na si dide, nwọn si lọ: Joṣua si paṣẹ fun awọn ti o lọ ṣe apejuwe ilẹ na, wipe, Ẹ lọ, ki ẹ si rìn ilẹ na já, ki ẹ si ṣe apejuwe rẹ̀, ki ẹ si pada tọ̀ mi wá, ki emi ki o le ṣẹ́ keké fun nyin niwaju OLUWA ni Ṣilo.
9Awọn ọkunrin na si lọ, nwọn si là ilẹ na já, nwọn si ṣe apejuwe rẹ̀ sinu iwé ni ilu ilu li ọ̀na meje, nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, si ibudó ni Ṣilo.
10Joṣua si ṣẹ́ keké fun wọn ni Ṣilo niwaju OLUWA: nibẹ̀ ni Joṣua si pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ipín wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Bẹnjamini
11Ilẹ ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini yọ jade, gẹgẹ bi idile wọn: àla ipín wọn si yọ si agbedemeji awọn ọmọ Juda ati awọn ọmọ Josefu.
12Àla wọn ni ìha ariwa si ti Jordani lọ; àla na si gòke lọ si ìha Jeriko ni ìha ariwa, o si là ilẹ òke lọ ni iwọ-õrùn; o si yọ si aginjù Beti-afeni.
13Àla na si ti ibẹ̀ lọ si Lusi, si ìha Lusi (ti ṣe Beti-eli), ni ìha gusù; àla na si sọkale lọ si Atarotu-adari, lẹba òke ti mbẹ ni gusù Beti-horoni isalẹ.
14A si fà àla na lọ, o si yi si ìha ìwọ-õrùn lọ si gusù, lati òke ti mbẹ niwaju Beti-horoni ni ìha gusù; o si yọ si Kiriati-baali (ti ṣe Kiriati-jearimu), ilu awọn ọmọ Juda kan: eyi ni apa ìwọ-õrùn.
15Ati apa gusù ni lati ipẹkun Kiriati-jearimu, àla na si yọ ìwọ-õrùn, o si yọ si isun omi Neftoa:
16Àla na si sọkalẹ lọ si ipẹkun òke ti mbẹ niwaju afonifoji ọmọ Hinnomu, ti o si mbẹ ni afonifoji Refaimu ni ìha ariwa; o si sọkalẹ lọ si afonifoji Hinnomu, si apa Jebusi ni ìha gusù, o si sọkalẹ lọ si Eni-rogeli;
17A si fà a lati ariwa lọ, o si yọ si Eni-ṣemeṣi, o si yọ si Gelilotu, ti o kọjusi òke Adummimu; o si sọkalẹ lọ si okuta Bohani ọmọ Reubeni;
18O si kọja lọ si apa ibi ti o kọjusi Araba ni ìha ariwa, o si sọkalẹ lọ si Araba:
19Àla na si kọja lọ dé apa Beti-hogla ni ìha ariwa: àla na si yọ ni ìha ariwa si kọ̀rọ Okun Iyọ̀, ni ipẹkun gusù ti Jordani: eyi ni àla gusù.
20Jordani si ni àla rẹ̀ ni ìha ìla-õrùn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini, li àgbegbe rẹ̀ kakiri, gẹgẹ bi idile wọn.
21Njẹ ilu ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn, ni Jeriko, ati Beti-hogla, ati Emekikesisi;
22Ati Beti-araba, ati Semaraimu, ati Beti-eli;
23Ati Affimu, ati Para, ati Ofra;
24Ati Kefari-ammoni, ati Ofni, ati Geba; ilu mejila pẹlu ileto wọn:
25Gibeoni, ati Rama, ati Beerotu;
26Ati Mispe, ati Kefira, ati Mosa;
27Ati Rekemu, ati Irpeeli, ati Tarala;
28Ati Sela, Elefu, ati Jebusi (ti iṣe Jerusalemu), Gibeati, ati Kitiria; ilu mẹrinla pẹlu ileto wọn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Joṣ 18: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀