Joṣ 17

17
Ilẹ̀ Ẹ̀yà Manase ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn
1EYI si ni ipín ẹ̀ya Manasse; nitori on li akọ́bi Josefu. Bi o ṣe ti Makiri akọ́bi Manasse, baba Gileadi, nitori on ṣe ologun, nitorina li o ṣe ní Gileadi ati Baṣani.
2Awọn ọmọ Manasse iyokù si ní ilẹ-iní gẹgẹ bi idile wọn; awọn ọmọ Abieseri, ati awọn ọmọ Heleki, ati awọn ọmọ Asrieli, ati awọn ọmọ Ṣekemu, ati awọn ọmọ Heferi, ati awọn ọmọ Ṣemida: awọn wọnyi ni awọn ọmọ Manasse ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn.
3Ṣugbọn Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, kò ní ọmọkunrin, bikoṣe ọmọbinrin: awọn wọnyi si li orukọ awọn ọmọbinrin rẹ̀, Mala, ati Noa, Hogla, Milka, ati Tirsa.
4Nwọn si wá siwaju Eleasari alufa, ati siwaju Joṣua ọmọ Nuni, ati siwaju awọn olori, wipe, OLUWA fi aṣẹ fun Mose lati fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin wa: nitorina o fi ilẹ-iní fun wọn lãrin awọn arakunrin baba wọn, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA.
5Ipín mẹwa si bọ́ sọdọ Manasse, làika ilẹ Gileadi ati Baṣani, ti mbẹ ni ìha keji Jordani;
6Nitoriti awọn ọmọbinrin Manasse ní ilẹ-iní lãrin awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin: awọn ọmọ Manasse ọkunrin iyokù si ní ilẹ Gileadi.
7Àla Manasse si lọ lati Aṣeri dé Mikmeta, ti mbẹ niwaju Ṣekemu; àla na si lọ titi ni ìha ọtún, sọdọ awọn ara Eni-tappua.
8Manasse li o ní ilẹ Tappua: ṣugbọn Tappua li àla Manasse jẹ́ ti awọn ọmọ Efraimu.
9Àla rẹ̀ si sọkalẹ lọ si odò Kana, ni ìha gusù odò na: ilu Efraimu wọnyi wà lãrin awọn ilu Manasse: àla Manasse pẹlu si wà ni ìha ariwa odò na, o si yọ si okun:
10Ni ìha gusù ti Efraimu ni, ati ni ìha ariwa ti Manasse ni, okun si ni àla rẹ̀; nwọn si dé Aṣeri ni ìha ariwa, ati Issakari ni ìha ìla-õrùn.
11Manasse si ní ni Issakari ati ni Aṣeri, Beti-ṣeani ati awọn ilu rẹ̀, ati Ibleamu ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Dori ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Enidori ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Taanaki ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Megiddo ati awọn ilu rẹ̀, ani òke mẹta na.
12Ṣugbọn awọn ọmọ Manasse kò le gbà ilu wọnyi; awọn ara Kenaani si ngbé ilẹ na.
13O si ṣe, nigbati awọn ọmọ Israeli ndi alagbara, nwọn mu awọn ara Kenaani sìn, ṣugbọn nwọn kò lé wọn jade patapata.
Ẹ̀yà Efraimu ati ti Manase ti Ìwọ̀ Oòrùn Bèèrè fún Ilẹ̀ Sí i
14Awọn ọmọ Josefu si wi fun Joṣua pe, Ẽṣe ti iwọ fi fun mi ni ilẹ kan, ati ipín kan ni ilẹ-iní, bẹ̃ni enia nla ni mi, niwọnbi OLUWA ti bukún mi titi di isisiyi?
15Joṣua si da wọn lohùn pe, Bi iwọ ba jẹ́ enia nla, gòke lọ si igbó, ki o si ṣanlẹ fun ara rẹ nibẹ̀ ni ilẹ awọn Perissi ati ti Refaimu; bi òke Efraimu ba há jù fun ọ.
16Awọn ọmọ Josefu si wipe, Òke na kò to fun wa: gbogbo awọn ara Kenaani ti ngbé ilẹ afonifoji si ní kẹkẹ́ irin, ati awọn ti mbẹ ni Beti-ṣeani, ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ti mbẹ ni afonifoji Jesreeli.
17Joṣua si wi fun ile Josefu, ani fun Efraimu ati fun Manasse pe, Enia nla ni iwọ, iwọ si lí agbara pipọ̀: iwọ ki yio ní ipín kanṣoṣo:
18Ṣugbọn ilẹ òke yio jẹ́ tirẹ; nitoriti iṣe igbó, iwọ o si ṣán a, ati ìna rẹ̀ yio jẹ́ tirẹ: nitoriti iwọ o lé awọn ara Kenaani jade, bi o ti jẹ́ pe nwọn ní kẹkẹ́ irin nì, ti o si jẹ́ pe nwọn lí agbara.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Joṣ 17: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀