Joṣ 12

12
Àwọn Ọba Tí Mose Ṣẹgun
1NJẸ wọnyi ni awọn ọba ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli pa, ti nwọn si gbà ilẹ wọn li apa keji Jordani, ni ìha ìla-õrùn, lati odò Arnoni lọ titi dé òke Hermoni, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ni ìha ìla-õrun:
2Sihoni ọba Amori, ti ngbé Heṣboni, ti o si jọba lati Aroeri, ti mbẹ leti odò Arnoni, ati ilu ti o wà lãrin afonifoji na, ati àbọ Gileadi, ani titi dé odò Jaboku, àgbegbe awọn ọmọ Ammoni;
3Ati ni pẹtẹlẹ̀ lọ dé okun Kinnerotu ni ìha ìla-õrùn, ati titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀ ni ìha ìla-õrun, li ọ̀na Beti-jeṣimotu; ati lati gusù lọ nisalẹ ẹsẹ̀-òke Pisga:
4Ati àgbegbe Ogu ọba Baṣani, ọkan ninu awọn ti o kù ninu awọn Refaimu, èniti ngbé Aṣtarotu ati Edrei,
5O si jọba li òke Hermoni, ati ni Saleka, ati ni gbogbo Baṣani, titi o fi dé àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati àbọ Gileadi, àla Sihoni ọba Heṣboni.
6Mose iranṣẹ OLUWA ati awọn ọmọ Israeli kọlù wọn: Mose iranṣẹ OLUWA si fi i fun awọn ọmọ Reubeni ni ilẹ-iní, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.
Àwọn Ọba Tí Joṣua Ṣẹgun
7Wọnyi li awọn ọba ilẹ na, ti Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa li apa ihin Jordani, ni ìwọ-õrùn, lati Baali-gadi li afonifoji Lebanoni ani titidé òke Halaki, li ọ̀na òke Seiri; ti Joṣua fi fun awọn ẹ̀ya Israeli ni ilẹ-iní gẹgẹ bi ipín wọn.
8Ni ilẹ òke, ati ni ilẹ titẹju, ati ni pẹtẹlẹ̀, ati li ẹsẹ̀-òke, ati li aginjù, ati ni Gusù; awọn Hitti, awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi:
9Ọba Jeriko, ọkan; ọba Ai, ti o wà lẹba Beti-eli, ọkan.
10Ọba Jerusalemu, ọkan; ọba Hebroni, ọkan;
11Ọba Jarmutu, ọkan; ọba Lakiṣi, ọkan;
12Ọba Egloni, ọkan; ọba Geseri, ọkan;
13Ọba Debiri, ọkan; ọba Gederi, ọkan;
14Ọba Horma, ọkan; ọba Aradi, ọkan;
15Ọba Libna, ọkan; ọba Adullamu, ọkan;
16Ọba Makkeda, ọkan; ọba Betieli, ọkan;
17Ọba Tappua, ọkan; ọba Heferi, ọkan;
18Ọba Afeki, ọkan; ọba Laṣaroni, ọkan;
19Ọba Madoni, ọkan; ọba Hasoru, ọkan;
20Ọba Ṣimroni-meroni, ọkan; ọba Akṣafu, ọkan;
21Ọba Taanaki, ọkan; ọba Megiddo, ọkan;
22Ọba Kedeṣi, ọkan; ọba Jokneamu ti Karmeli, ọkan;
23Ọba Doru, li òke Doru, ọkan; ọba awọn orilẹ-ède Gilgali, ọkan;
24Ọba Tirsa, ọkan; gbogbo awọn ọba na jẹ́ mọkanlelọgbọ̀n.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Joṣ 12: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa