Ki yio sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo: gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o si wà pẹlu rẹ: Emi ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃li emi ki yio kọ̀ ọ. Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitori iwọ ni yio pín ilẹ na fun awọn enia yi, ilẹ ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn. Sá ṣe giri ki o si mu àiya le gidigidi, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi ti palaṣẹ fun ọ: má ṣe yà kuro ninu rẹ̀ si ọtún tabi si òsi, ki o le dara fun ọ nibikibi ti iwọ ba lọ.
Kà Joṣ 1
Feti si Joṣ 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joṣ 1:5-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò