Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ Jona wá lẹ̃keji, wipe, Dide, lọ si Ninefe, ilu nla nì, ki o si kede si i, ikede ti mo sọ fun ọ. Jona si dide, o si lọ si Ninefe, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa. Ninefe si jẹ ilu nla gidigidi tó irin ijọ mẹta. Jona si bẹrẹsi wọ inu ilu na lọ ni irin ijọ kan, o si kede, o si wipe, Niwọn ogoji ọjọ si i, a o bì Ninefe wo. Awọn enia Ninefe si gba Ọlọrun gbọ́, nwọn si kede awẹ̀, nwọn si wọ aṣọ ọ̀fọ, lati agbà wọn titi de kekere wọn.
Kà Jon 3
Feti si Jon 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jon 3:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò