JOBU si dahùn o si wipe, A! a ba le iwọ̀n ibinujẹ mi ninu òṣuwọn, ki a si le igbe ọ̀fọ mi le ori òṣuwọn ṣọkan pọ̀! Njẹ nisisiyi, iba wuwo jù iyanrin okun lọ: nitorina li ọ̀rọ mi ṣe ntàse. Nitoripe ọfa Olodumare wọ̀ mi ninu, oró eyiti ọkàn mi mu; ipaiya-ẹ̀ru Ọlorun dotì mi. Kẹtẹkẹtẹ ìgbẹ a ma dún, nigbati o ba ni koriko, tabi ọdá-malu a ma dún sori ijẹ rẹ̀? A le jẹ ohun ti kò li adùn li aini iyọ̀, tabi adùn wà ninu funfun ẹyin? Ohun ti ọkàn mi kọ̀ lati tọ́, on li o dàbi onjẹ mi ti kò ni adùn. A! emi iba lè ri iberè mi gbà; ati pe, ki Ọlọrun le fi ohun ti emi ṣafẹri fun mi. Ani, Ọlọrun iba jẹ pa mi run, ti on iba jẹ ṣiwọ rẹ̀ ki o si ké mi kuro. Nigbana ni emi iba ni itunú sibẹ, ani emi iba mu ọkàn mi le ninu ibinujẹ mi ti kò da ni si: nitori emi kò fi ọ̀rọ Ẹni Mimọ́ nì sin ri. Kili agbara mi ti emi o fi dabá? ki si li opin mi ti emi o fi fà ẹmi mi gùn? Agbara mi iṣe agbara okuta bi, tabi ẹran ara mi iṣe idẹ? Iranlọwọ mi kò ha wà ninu mi: ọgbọn ha ti salọ kuro lọdọ mi bi? Ẹniti aya rẹ̀ yọ́ danu tan ni a ba ma ṣãnu fun lati ọdọ ọrẹ rẹ̀ wá, ki o má kọ̀ ibẹru Olodumare silẹ̀. Awọn ará mi ṣẹ̀tan bi odò ṣolõ, bi iṣàn gburu omi odò ṣolõ, nwọn ṣàn kọja lọ. Ti o dúdu nitori omi didì, ati nibiti òjo didì gbe lùmọ si.
Kà Job 6
Feti si Job 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 6:1-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò