Bẹ̃li o si ri, lẹhin igbati OLUWA ti sọ ọ̀rọ wọnyi tan fun Jobu, OLUWA si wi fun Elifasi, ara Tema pe, Mo binu si ọ ati si awọn ọrẹ́ rẹ mejeji, nitoripe ẹnyin kò sọ̀rọ niti emi, ohun ti o tọ́ bi Jobu iranṣẹ mi ti sọ. Nitorina ẹ mu akọ ẹgbọrọ malu meje, ati àgbo meje, ki ẹ si tọ̀ Jobu iranṣẹ mi lọ, ki ẹ si fi rú ẹbọ sisun fun ara nyin: Jobu iranṣẹ mi yio si gbadura fun nyin: nitoripe oju rẹ̀ ni mo gbà; ki emi ki o má ba ṣe si nyin bi iṣina nyin, niti ẹnyin kò sọ̀rọ ohun ti o tọ́ si mi bi Jobu iranṣẹ mi. Bẹ̃ni Elifasi, ara Tema, ati Bildadi, ara Ṣua, ati Sofari, ara Naama lọ, nwọn si ṣe gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: OLUWA si gbà oju Jobu.
Kà Job 42
Feti si Job 42
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 42:7-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò