OLUWA si yi igbekun Jobu pada, nigbati o gbadura fun awọn ọrẹ rẹ̀: OLUWA si busi ohun gbogbo ti Jobu ni rí ni iṣẹpo meji. Nigbana ni gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn arabinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ti o ti ṣe ojulumọ rẹ̀ rí, nwọn mba a jẹun ninu ile rẹ̀, nwọn si ṣe idaro rẹ̀, nwọn si ṣipẹ fun nitori ibí gbogbo ti OLUWA ti mu ba a: olukuluku enia pẹlu si bùn u ni ike owo-kọkan ati olukuluku ni oruka wura eti kọ̃kan. Bẹ̃li OLUWA bukún igbẹhin Jobu jù iṣaju rẹ̀ lọ; o si ni ẹgba-meje agutan, ẹgba-mẹta ibakasiẹ, ati ẹgbẹrun ajaga ọda-malu, ati ẹgbẹrun abo kẹtẹkẹtẹ. O si ni ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta. O si sọ orukọ akọbi ni Jemima, ati orukọ ekeji ni Kesia, ati orukọ ẹkẹta ni Keren-happuki. Ati ni gbogbo ilẹ na, a kò ri obinrin ti o li ẹwa bi ọmọbinrin Jobu; baba wọn si pinlẹ fun wọn ninu awọn arakunrin wọn. Lẹhin eyi Jobu wà li aiye li ogoje ọdun, o si ri awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ani iran mẹrin. Bẹ̃ni Jobu kú, o gbó, o si kún fun ọjọ.
Kà Job 42
Feti si Job 42
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 42:10-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò