OLUWA da Jobu lohùn si i pẹlu, o si wipe, Ẹniti mba Olodumare jà, yio ha kọ́ ọ li ẹkọ́? ẹniti mba Ọlọrun wi, jẹ ki o dahùn! Nigbana ni Jobu da Oluwa lohùn, o si wipe: Kiyesi i, ẹgbin li emi; ohùn kili emi o da? emi o fi ọwọ mi le ẹnu mi. Ẹ̃kan ni mo sọ̀rọ̀, ṣugbọn emi kì yio si tun sọ mọ, lẹ̃meji ni, emi kò si le iṣe e mọ́. Nigbana ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe: Di àmure giri li ẹgbẹ rẹ bi ọkunrin, emi o bi ọ lere, ki iwọ ki o si kọ́ mi li ẹkọ́. Iwọ ha fẹ imu idajọ mi di asan? iwọ o si da mi lẹbi, ki iwọ ki o le iṣe olododo? Iwọ ni apá bi Ọlọrun, tabi iwọ le ifi ohùn san ãrá bi on? Fi ọlanla ati ọla-itayọ ṣe ara rẹ li ọṣọ, ki o si fi ogo ati ẹwa ọṣọ bò ara rẹ li aṣọ. Mu irunu ibinu rẹ jade, kiyesi gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ. Wò gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ, ki o si tẹ enia buburu mọlẹ ni ipo wọn. Fi wọn sin pọ̀ ninu erupẹ, ki o si di oju wọn ni ikọkọ. Nigbana li emi o yìn ọ pe, ọwọ ọ̀tun ara rẹ le igba ọ la.
Kà Job 40
Feti si Job 40
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 40:1-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò