Nibo ni iwọ wà nigbati mo fi ipilẹ aiye sọlẹ? wi bi iwọ ba moye! Tali o fi ìwọn rẹ̀ lelẹ, bi iwọ ba mọ̀, tabi tani o ta okun wiwọn sori rẹ̀. Lori ibo ni a gbe kan ipilẹ rẹ̀ mọ́, tabi tali o fi okuta igun rẹ̀ le ilẹ? Nigbati awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ̀, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun nhó iho ayọ̀? Tabi tali o fi ilẹkun sé omi okun mọ́, nigbati o ya jade bi ẹnipe o ti inu tu jade wá? Nigbati mo fi awọsanma ṣe aṣọ rẹ̀, ati òkunkun ṣiṣu ṣe ọ̀ja igbanu rẹ̀? Ti mo ti paṣẹ ipinnu mi fun u, ti mo si ṣe bèbe ati ilẹkun. Ti mo si wipe, Nihinyi ni iwọ o dé, ki o má si rekọja, nihinyi si ni igberaga riru omi rẹ yio gbe duro mọ.
Kà Job 38
Feti si Job 38
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 38:4-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò