Nipa ẹmi Ọlọrun a fi ìdi-omi funni, ibu-omi a si sunkì. Pẹlupẹlu o fi omi pupọ mu awọsanma wuwo, a si tú awọsanma imọlẹ rẹ̀ ká. Awọn wọnyi ni a si yi kakiri nipa ilana rẹ̀, ki nwọn ki o le iṣe ohunkohun ti o pa fun wọn li aṣẹ loju aiye lori ilẹ. O mu u wá ibãṣe fun ikilọ̀ ni, tabi fun rere ilẹ rẹ̀, tabi fun ãnu. Jobu dẹtisilẹ si eyi, duro jẹ, ki o si rò iṣẹ iyanu Ọlọrun. Iwọ mọ̀ akoko ìgba ti Ọlọrun sọ wọn lọjọ̀, ti o si mu imọlẹ awọsanma rẹ̀ dán? Iwọ mọ̀ ọ̀na ti awọsanma ifo lọ; iṣẹ iyanu ẹniti o pé ni ìmọ? Aṣọ rẹ̀ ti ma gbona, nigbati o mu aiye dakẹ lati gusu wá. Iwọ ha ba a tẹ pẹpẹ oju-ọrun, ti o duro ṣinṣin, ti o si dabi digi ti o yọ́ dà. Kọ́ wa li eyi ti a le iwi fun u; nitoripe awa kò le iladi ọ̀rọ nitori òkunkun. A o ha wi fun u pe, Emi fẹ sọ̀rọ? tabi ẹnikan wipe, Ifẹ mi ni pe ki a gbe mi mì? Sibẹ nisisiyi enia kò ri imọlẹ ti ndán ninu awọsanma, ṣugbọn afẹfẹ kọja, a si gbá wọn mọ́. Wura didan ti inu iha ariwa jade wá, lọdọ Ọlọrun li ọlanla ẹ̀ru-nla. Nipa ti Olodumare awa kò le iwadi rẹ̀ ri, o rekọja ni ipá, on kì iba idajọ ati ọ̀pọlọpọ otitọ jẹ. Nitorina enia a ma bẹ̀ru rẹ̀, on kì iṣojusaju ẹnikẹni ti o gbọ́n ni inu.
Kà Job 37
Feti si Job 37
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 37:10-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò