Job 33:8-27

Job 33:8-27 YBCV

Nitõtọ iwọ sọ li eti mi, emi si gbọ́ ọ̀rọ rẹ wipe, Emi mọ́, laini irekọja, alaiṣẹ li emi, bẹ̃li aiṣedede kò si li ọwọ mi. Kiyesi i, ẹ̀fẹ li o fẹ si mi, o kà mi si ọ̀ta rẹ̀. O kàn ẹsẹ mi sinu àba, o kiyesi ipa-irin mi gbogbo. Kiyesi i, ninu eyi iwọ ṣìna! emi o da ọ lohùn pe: Ọlọrun tobi jù enia lọ! Nitori kini iwọ ṣe mba a jà pe: on kì isọrọ̀kọrọ kan nitori iṣẹ rẹ̀? Nitoripe Ọlọrun sọ̀rọ lẹkan, ani lẹkeji ṣugbọn enia kò roye rẹ̀. Ninu àla, li ojuran oru, nigbati orun ìjika ba kùn enia lọ, ni isunyẹ lori bùsun. Nigbana ni iṣi eti enia, a si fi èdidi di ẹkọ wọn. Ki o lè ifa enia sẹhin kuro ninu ete rẹ̀, ki o si pa igberaga mọ́ kuro lọdọ enia. O si fa ọkàn rẹ̀ pada kuro ninu iho, ati ẹmi rẹ̀ lati ṣègbe lọwọ idà. A si fi irora nà a lori ibùsun rẹ̀, pẹlupẹlu a fi ijà egungun rẹ̀ ti o duro pẹ́, nà a. Bẹ̃li ẹmi rẹ̀ kọ̀ onjẹ, ati ọkàn rẹ̀ kọ̀ onjẹ didùn. Ẹran ara rẹ̀ rùn, titi a kò si fi lè ri i mọ́; egungun rẹ̀ ti a kò ri, si ta jade. Ani ọkàn rẹ̀ sunmọ isa-okú, ati ẹmi rẹ̀ sunmọ ọdọ awọn iranṣẹ ikú. Bi onṣẹ kan ba wà lọdọ rẹ̀, ẹniti nṣe alagbawi, ọkan ninu ẹgbẹrun lati fi ọ̀na pipé han ni: Nigbana ni o ṣore-ọfẹ fun u, o si wipe, Gbà a kuro ninu ilọ sinu ihò, emi ti ri irapada! Ara rẹ̀ yio si já yọ̀yọ̀ jù ti ọmọ kekere, yio si tún pada si ọjọ igba ewe rẹ̀. O gbadura sọdọ Ọlọrun, on o si ṣe oju rere si i, o si mu enia ri oju rẹ̀ pẹlu ayọ̀, on o san ododo rẹ̀ pada fun enia. O bojuwo enia, bi ẹnikan ba si wipe, Emi ṣẹ̀, mo si ti yi eyi ti o tọ́ po, a kò si sẹsan rẹ̀ fun mi