ṢUGBỌN Jobu si dahùn wipe, Bawo ni iwọ nṣe iranlọwọ ẹniti kò ni ipá, bawo ni iwọ nṣe gbà apa ẹniti kò li agbara? Bawo ni iwọ nṣe ìgbimọ ẹniti kò li ọgbọ́n, tabi bawo ni iwọ nsọdi ọ̀ran li ọ̀pọlọpọ bi o ti ri? Tani iwọ mbà sọ̀rọ, ati ẹmi tani o ti ọdọ rẹ wá? Awọn alailagbara ti isa-okú wáriri; labẹ omi pẹlu awọn ti ngbe inu rẹ̀. Ihoho ni ipo-okú niwaju rẹ̀, ibi iparun kò si ni iboju. On ni o nà ìha ariwa ọrun ni ibi ofurufu, o si fi aiye rọ̀ li oju ofo. O di omiyomi pọ̀ ninu awọsanma rẹ̀ ti o nipọn; awọsanma kò si ya nisalẹ wọn. O si fa oju itẹ rẹ̀ sẹhin, o si tẹ awọ sanma rẹ̀ si i lori. O fi ìde yi omi-okun ka, titi de ala imọlẹ ati òkunkun. Ọwọn òpo ọrun wáriri, ẹnu si yà wọn si ibawi rẹ̀. O fi ipa rẹ̀ damu omi-okun, nipa oye rẹ̀ o lu agberaga jalẹjalẹ. Nipa ẹmi rẹ li o ti ṣe ọrun li ọ̀ṣọ, ọwọ rẹ̀ li o ti da ejo-wiwọ́ nì. Kiyesi i, eyi ni opin ọ̀na rẹ̀, ohùn eyiti a gbọ́ ti kere tó! ṣugbọn ãra ipá rẹ̀ tali oye rẹ̀ le iye?
Kà Job 26
Feti si Job 26
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 26:1-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò