Job 26

26
1ṢUGBỌN Jobu si dahùn wipe,
2Bawo ni iwọ nṣe iranlọwọ ẹniti kò ni ipá, bawo ni iwọ nṣe gbà apa ẹniti kò li agbara?
3Bawo ni iwọ nṣe ìgbimọ ẹniti kò li ọgbọ́n, tabi bawo ni iwọ nsọdi ọ̀ran li ọ̀pọlọpọ bi o ti ri?
4Tani iwọ mbà sọ̀rọ, ati ẹmi tani o ti ọdọ rẹ wá?
5Awọn alailagbara ti isa-okú wáriri; labẹ omi pẹlu awọn ti ngbe inu rẹ̀.
6Ihoho ni ipo-okú niwaju rẹ̀, ibi iparun kò si ni iboju.
7On ni o nà ìha ariwa ọrun ni ibi ofurufu, o si fi aiye rọ̀ li oju ofo.
8O di omiyomi pọ̀ ninu awọsanma rẹ̀ ti o nipọn; awọsanma kò si ya nisalẹ wọn.
9O si fa oju itẹ rẹ̀ sẹhin, o si tẹ awọ sanma rẹ̀ si i lori.
10O fi ìde yi omi-okun ka, titi de ala imọlẹ ati òkunkun.
11Ọwọn òpo ọrun wáriri, ẹnu si yà wọn si ibawi rẹ̀.
12O fi ipa rẹ̀ damu omi-okun, nipa oye rẹ̀ o lu agberaga jalẹjalẹ.
13Nipa ẹmi rẹ li o ti ṣe ọrun li ọ̀ṣọ, ọwọ rẹ̀ li o ti da ejo-wiwọ́ nì.
14Kiyesi i, eyi ni opin ọ̀na rẹ̀, ohùn eyiti a gbọ́ ti kere tó! ṣugbọn ãra ipá rẹ̀ tali oye rẹ̀ le iye?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 26: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀