Kiyesi i, emi mọ̀ iro inu nyin ati arekereke ti ẹnyin fi gba dulumọ si mi. Nitoriti ẹnyin wipe, nibo ni ile awọn ọmọ alade, ati nibo ni agọ awọn enia buburu nì gbe wà? Ẹnyin kò bere lọwọ awọn ti nkọja lọ li ọ̀na, ẹnyin kò mọ̀ àmi wọn? pe, Enia buburu ni a fi pamọ fun ọjọ iparun, a o si mu wọn jade li ọjọ riru ibinu. Tani yio sọ ipa-ọ̀na rẹ̀ kò o li oju, tani yio si san pada fun u li eyi ti o ti ṣe? Sibẹ a o si sin i li ọ̀na ipo-okú, yio si ma ṣọ́ ororì okú. Ogulutu ọfin yio dùn mọ ọ, gbogbo enia yio si ma tọ̀ ọ lẹhin, bi enia ainiye ti lọ ṣiwaju rẹ̀. E ha ti ṣe ti ẹnyin fi ntù mi ninu lasan! bi o ṣepe ni idahùn nyin eké kù nibẹ.
Kà Job 21
Feti si Job 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 21:27-34
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò