O si tun di ijọ kan nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wá ipé niwaju Oluwa, Satani si wá pẹlu wọn, lati pé niwaju Oluwa.
Oluwa si bi Satani pe, nibo ni iwọ ti wá? Satani si dá Oluwa lohùn pe, lati ilọ siwá sẹhin lori ilẹ aiye ati ni irinkerindo ninu rẹ̀.
Oluwa si wi fun Satani pe, iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ li aiye, ọkunrin ti iṣe olõtọ ti o si duro ṣinṣin, ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun ti o si korira ìwa buburu, bẹ̃li o si di ìwa otitọ rẹ̀ mu ṣinṣin, bi iwọ tilẹ ti dẹ mi si i lati run u lainidi.
Satani si dá Oluwa lohùn wipe, awọ fun awọ; ani ohun gbogbo ti enia ni, on ni yio fi rà ẹmi rẹ̀.
Ṣugbọn nawọ rẹ nisisiyi, ki o si fi tọ́ egungun rẹ̀ ati ara rẹ̀, bi kì yio si bọhùn li oju rẹ.
Oluwa si wi fun Satani pe, Wõ, o mbẹ ni ikawọ rẹ, ṣugbọn dá ẹmi rẹ̀ si.
Bẹ̃ni Satani jade lọ kuro niwaju Oluwa, o si sọ Jobu li õwo kikankikan lati atẹlẹsẹ rẹ̀ lọ de atari rẹ̀.
O si mu apadì o fi nhá ara rẹ̀, o si joko ninu ẽru.
Nigbana ni aya rẹ̀ wi fun u pe, iwọ di ìwa otitọ rẹ mu sibẹ! bu Ọlọrun, ki o si kú.
Ṣugbọn on da a lohùn pe, iwọ sọ̀rọ bi ọkan ninu awọn obinrin alaimoye ti isọ̀rọ; kinla! awa o ha gba ire lọwọ Ọlọrun, ki a má si gba ibi! Ninu gbogbo eyi Jobu kò fi ète rẹ̀ ṣẹ̀.
Nigbati awọn ọrẹ Jobu mẹta gburo gbogbo ibi ti o ba a, nwọn wá, olukuluku lati ibujoko rẹ̀ wá; Elifasi, ara Tema, a si Bildadi, ara Ṣua, ati Sofari, ara Naama: nitoripe nwọn ti dajọ ipade pọ̀ lati ba a ṣọ̀fọ on ati ṣipẹ fun u.
Nigbati nwọn si gboju wọn wò li òkere rére, ti nwọn kò si mọ̀ ọ, nwọn gbe ohùn wọn soke, nwọn sọkun: olukuluku si fa aṣọ igunwa rẹ̀ ya, nwọn si kù erupẹ si oju ọrun si ara wọn lori.
Bẹ̃ni nwọn joko tì i ni ilẹyilẹ ni ijọ meje ti ọ̀san ti oru, ẹnikẹni kò si ba a dá ọ̀rọ kan sọ nitoriti nwọn ri pe, ibinujẹ rẹ̀ pọ̀ gidigidi.