A! Ibaṣepe a le kọwe ọ̀rọ mi nisisiyi, ibaṣepe a le dà a sinu iwe! Ki a fi kalamu irin ati ti ojé kọ́ wọn sinu apata fun lailai. Ati emi, emi mọ̀ pe Oludande mi mbẹ li ãyè, ati pe on bi Ẹni-ikẹhin ni yio dide soke lori erupẹ ilẹ. Ati lẹhin igba awọ ara mi, ti a ti ke e kuro bi iru eyi, ati laili ẹran ara mi li emi o ri Ọlọrun, Ẹniti emi o ri fun ara mi, ti oju mi o si wò, kì si iṣe ti ẹlomiran; ọkàn mi si dáku ni inu mi. Bi ẹnyin ba wipe, Awa o ti lepa rẹ̀ to! ati pe, gbongbo ọ̀rọ na li a sa ri li ọwọ mi, Ki ẹnyin ki o bẹ̀ru idà; nitoripe ibinu ni imu ijiya idà wá: ki ẹnyin ki o lè imọ̀ pe idajọ kan mbẹ.
Kà Job 19
Feti si Job 19
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 19:23-29
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò