Wò o, oju mi ti ri gbogbo eyi ri, eti mi si gbọ́ o si ti ye e. Ohun ti ẹnyin mọ̀, emi mọ̀ pẹlu, emi kì iṣe ọmọ-ẹhin nyin. Nitotọ emi o ba Olodumare sọ̀rọ, emi si nfẹ ba Ọlọrun sọ asọye. Ẹnyin ni onihumọ eke, oniṣegun lasan ni gbogbo nyin. O ṣe! ẹ ba kuku pa ẹnu nyin mọ patapata! eyini ni iba si ṣe ọgbọ́n nyin. Ẹ gbọ́ awiye mi nisisiyi, ẹ si fetisilẹ si aroye ẹnu mi. Ẹnyin fẹ sọ isọkusọ fun Ọlọrun? ki ẹ si fi ẹ̀tan sọ̀rọ gbè e? Ẹnyin fẹ ṣojusaju rẹ̀, ẹnyin fẹ igbìjà fun Ọlọrun? O ha dara ti yio fi hudi nyin silẹ, tabi ki ẹnyin tàn a bi ẹnikan ti itan ẹnikeji. Yio ma ba nyin wi nitotọ, bi ẹnyin ba ṣojusaju enia nikọ̀kọ. Iwa ọlá rẹ̀ ki yio bà nyin lẹ̃ru bi? ipaiya rẹ̀ ki yio pá nyin laiya? Iranti nyin dabi ẽru, ilu-odi nyin dabi ilu-odi amọ̀.
Kà Job 13
Feti si Job 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 13:1-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò