Job 13

13
1Wò o, oju mi ti ri gbogbo eyi ri, eti mi si gbọ́ o si ti ye e.
2Ohun ti ẹnyin mọ̀, emi mọ̀ pẹlu, emi kì iṣe ọmọ-ẹhin nyin.
3Nitotọ emi o ba Olodumare sọ̀rọ, emi si nfẹ ba Ọlọrun sọ asọye.
4Ẹnyin ni onihumọ eke, oniṣegun lasan ni gbogbo nyin.
5O ṣe! ẹ ba kuku pa ẹnu nyin mọ patapata! eyini ni iba si ṣe ọgbọ́n nyin.
6Ẹ gbọ́ awiye mi nisisiyi, ẹ si fetisilẹ si aroye ẹnu mi.
7Ẹnyin fẹ sọ isọkusọ fun Ọlọrun? ki ẹ si fi ẹ̀tan sọ̀rọ gbè e?
8Ẹnyin fẹ ṣojusaju rẹ̀, ẹnyin fẹ igbìjà fun Ọlọrun?
9O ha dara ti yio fi hudi nyin silẹ, tabi ki ẹnyin tàn a bi ẹnikan ti itan ẹnikeji.
10Yio ma ba nyin wi nitotọ, bi ẹnyin ba ṣojusaju enia nikọ̀kọ.
11Iwa ọlá rẹ̀ ki yio bà nyin lẹ̃ru bi? ipaiya rẹ̀ ki yio pá nyin laiya?
12Iranti nyin dabi ẽru, ilu-odi nyin dabi ilu-odi amọ̀.
13Ẹ pa ẹnu nyin mọ kuro lara mi, ki emi ki o le sọ̀rọ, ohun ti mbọ̀ wá iba mi, ki o ma bọ̀.
14Njẹ nitori kili emi ṣe nfi ehin mi bù ẹran ara mi jẹ, ti mo si gbe ẹmi mi le ara mi lọwọ?
15Bi o tilẹ pa mi, sibẹ emi o ma gbẹkẹle e, ṣugbọn emi o ma tẹnumọ ọ̀na mi niwaju rẹ̀.
16Eyi ni yio si ṣe igbala mi pe: àgabagebe kì yio wá siwaju rẹ̀.
17Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ẹnu mi ni ifaiyabalẹ, ati asọpe mi li eti nyin.
18Wò o nisisiyi emi ti ladi ọ̀ran mi silẹ; emi mọ̀ pe a ó da mi lare.
19Tani on ti yio ba mi ṣàroye? njẹ nisisiyi, emi fẹ pa ẹnu mi mọ, emi o si jọwọ ẹmi mi lọwọ.
20Ṣugbọn ọkan ni, máṣe ṣe ohun meji yi si mi, nigbana ni emi kì yio si fi ara mi pamọ, kuro fun ọ,
21Fa ọwọ rẹ sẹhin kuro lara mi; má si jẹ ki ẹ̀ru rẹ ki o pá mi laiya.
22Nigbana ni ki iwọ ki o pè, emi o si dahùn, tabi jẹ ki nma sọ̀rọ, ki iwọ ki o si da mi lohùn.
23Melo li aiṣedede ati ẹ̀ṣẹ mi, mu mi mọ̀ irekọja ati ẹ̀ṣẹ mi!
24Nitori kini iwọ ṣe pa oju rẹ mọ́, ti o si yàn mi li ọta rẹ?
25Iwọ o fa ewe ya ti afẹfẹ nfẹ sihin sọhun: iwọ a si ma lepa akemọlẹ poroporo gbigbẹ!
26Nitoripe iwọ kọwe ohun kikoro si mi, o si mu mi ni aiṣedede ewe mi.
27Iwọ kàn àba mọ mi lẹsẹ pẹlu, iwọ si nwò ipa ọ̀na irin mi li awofin, iwọ si nfi ãlà yi gigisẹ mi ka.
28Ani, yi ẹniti a ti run ka, bi ohun ti o bu, bi aṣọ ti kòkoro jẹ bajẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 13: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa