Job 12

12
1JOBU si dahùn o si wipe,
2Kò si ani-ani nibẹ̀, ṣugbọn ẹnyin li awọn enia na, ọgbọ́n yio si kú pẹlu nyin.
3Ṣugbọn emi ni iyè ninu gẹgẹ bi ẹnyin: emi kì iṣe ọmọ-ẹhin nyin: ani, tani kò mọ̀ nkan bi iru wọnyi?
4Emi dabi ẹniti a nfi ṣe ẹlẹya lọdọ aladugbo rẹ̀, ti o kepe Ọlọrun, ti o si da a lohùn: a nfi olõtọ ẹni-iduro-ṣinṣin rẹrin ẹlẹyà.
5Ẹgan ni ẹni-òtoṣi, ti ẹsẹ rẹ̀ mura tan lati yọ́ ninu ìro ẹniti ara rọ̀.
6Agọ awọn igara ngberú, awọn ti o si nmu Ọlọrun binu wà lailewu, awọn ẹniti o si gbá oriṣa mu li ọwọ wọn.
7Ṣugbọn nisisiyi, bi awọn ẹranko lere, nwọn o kọ́ ọ li ẹkọ́, ati ẹiyẹ oju ọrun, nwọn o si sọ fun ọ.
8Tabi, ba ilẹ aiye sọ̀rọ, yio si kọ́ ọ, awọn ẹja inu okun yio si sọ fun ọ.
9Tani kò mọ̀ ninu gbogbo wọnyi pe, ọwọ Oluwa li o ṣe nkan yi?
10Lọwọ ẹniti ẹmi ohun alãye gbogbo gbé wà, ati ẹmi gbogbo araiye.
11Eti ki idán ọ̀rọ wò bi? tabi adùn ẹnu ki isi tọ onjẹ rẹ̀ wò?
12Awọn arugbo li ọgbọ́n wà fun, ati ninu gigùn ọjọ li oye.
13Pẹlu rẹ̀ (Ọlọrun) li ọgbọ́n ati agbarà, on ni ìmọ ati oye,
14Kiyesi i, o biwó, a kò si le igbe ró mọ́, o se enia mọ́, kò si sí iṣisilẹ̀ kan.
15Kiyesi i, o da awọn omi duro, nwọn si gbẹ, o si rán wọn jade, nwọn si ṣẹ bo ilẹ aiye yipo.
16Pẹlu rẹ̀ li agbara ati ọgbọ́n, ẹniti nṣìna ati ẹniti imu ni ṣìna tirẹ̀ ni nwọn iṣe.
17O mu awọn igbimọ̀ lọ nihoho, a si sọ awọn onidajọ di wère.
18O tu ide ọba, o si fi àmure gbà wọn li ọ̀ja.
19O mu awọn alufa lọ nihoho, o si tẹ ori awọn alagbara bá.
20O mu ọ̀rọ-ẹnu ẹni-igbẹkẹle kuro, o si ra awọn àgbàgbà ni iye.
21O bù ẹ̀gan lu awọn ọmọ-alade, o si tú àmure awọn alagbara.
22O hudi ohun ti o sigbẹ jade lati inu òkunkun wá, o si mu ojiji ikú jade wá sinu imọlẹ̀.
23On a mu orilẹ-ède bi si i, a si run wọn, on a sọ orilẹ-ède di nla, a si tun ṣẹ́ wọn kù.
24On a gbà aiya olú awọn enia aiye, a si ma mu wọn wọ́ kakiri ninu iju nibiti ọ̀na kò si.
25Nwọn a ma fi ọwọ ta ilẹ ninu òkunkun laisi imọlẹ, on a si ma mu wọn tàse irin bi ọmuti.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 12: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa