Job 11

11
1NIGBANA ni Sofari, ara Naama, dahùn o si wipe,
2A le iṣe ki a má ṣe dahùn si ọ̀pọlọpọ ọ́rọ, a ha si le dare fun ẹniti ẹnu rẹ̃ kún fun ọ̀rọ sisọ?
3Amọ̀tan rẹ le imu enia pa ẹnu wọn mọ bi? bi iwọ ba yọṣuti si ni, ki ẹnikẹni ki o má si doju tì ọ bi?
4Nitori iwọ sa ti wipe, ọ̀rọ ẹkọ́ mi mọ́, emi si mọ́ li oju rẹ.
5Ṣugbọn o ṣe! Ọlọrun iba jẹ sọ̀rọ, ki o si ya ẹnu rẹ̀ si ọ lara.
6Ki o si fi aṣiri ọgbọ́n hàn ọ pe, o pọ̀ jù oye enia lọ; nitorina mọ̀ pe: Ọlọrun kò bere to bi ẹbi rẹ.
7Iwọ ha le fi awari ri idi Ọlọrun? iwọ le ri idi Olodumare de pipé rẹ̀?
8O dabi giga ọrun, kini iwọ le iṣe? o jinlẹ jù ipo-okú lọ, kini iwọ le imọ̀?
9Ìwọn rẹ̀ gùn jù aiye lọ, o si ni ìbu jù okun lọ.
10Bi on ba rekọja, ti o si sénà, tabi ti o si ṣe ikojọpọ, njẹ tani yio da a pada kuro?
11On sa mọ̀ enia asan, o ri ìwa-buburu pẹlu, on kò si ni ṣe lãlã lati ṣà a rò.
12Enia lasan a sa ma fẹ iṣe ọlọgbọ́n, bi a tilẹ ti bi enia bi ọmọ kẹtẹkẹtẹ.
13Bi iwọ ba tun ọkàn rẹ ṣe, ti iwọ si nawọ rẹ sọdọ rẹ̀.
14Bi aiṣedede kan ba mbẹ lọwọ rẹ, mu u kuro si ọ̀na jijin rére, máṣe jẹ ki iwàkiwa kó wà ninu agọ rẹ.
15Nigbana ni iwọ o gbe oju rẹ soke laini abawọn, ani iwọ o duro ṣinṣin, iwọ kì yio si bẹ̀ru.
16Nitoripe iwọ o gbagbe òṣi rẹ, iwọ o si ranti rẹ̀ bi omi ti o ti ṣàn kọja lọ.
17Ọjọ aiye rẹ yio si mọlẹ jù ọsan gangan lọ, bi okunkun tilẹ bò ọ mọlẹ nisisiyi, iwọ o dabi owurọ̀.
18Iwọ o si wà lailewu, nitoripe ireti wà, ani iwọ o rin ilẹ rẹ wò, iwọ o si simi li alafia.
19Iwọ o si dubulẹ pẹlu kì yio si sí ẹniti yio dẹ̀ruba ọ, ani ọ̀pọ enia yio ma wá oju-rere rẹ.
20Ṣugbọn oju eniakenia yio mófo, nwọn kì yio le sala, ireti wọn a si dabi ẹniti o jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 11: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa