Njẹ, o di ọjọ kan, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wá ipé niwaju Oluwa, Satani si wá pẹlu wọn.
Oluwa si bi Satani wipe: nibo ni iwọ ti wá? nigbana ni Satani da Oluwa lohùn wipe: ni ilọ siwá sẹhin lori ilẹ aiye, ati ni irinkerindo ninu rẹ̀.
Oluwa si sọ fun Satani pe, Iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ li aiye, ọkunrin ti iṣe olõtọ, ti o si duro ṣinṣin, ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si korira ìwa buburu.
Nigbana ni Satani dá Oluwa lohùn wipe: Jobu ha bẹ̀ru Oluwa li asan bi?
Iwọ kò ha ti sọgbà yi i ká, ati yi ile rẹ̀ ati yi ohun ti o ni ká ni iha gbogbo? Iwọ busi iṣẹ ọwọ rẹ̀, ohunọ̀sin rẹ̀ si npọsi i ni ilẹ.
Njẹ nawọ rẹ nisisiyi, ki o si fi tọ́ ohun gbogbo ti o ni; bi kì yio si bọhùn li oju rẹ.
Oluwa si dá Satani lohùn wipe: kiyesi i, ohun gbogbo ti o ni mbẹ ni ikawọ rẹ, kìki on tikara rẹ̀ ni iwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ rẹ kàn: bẹ̃ni Satani jade lọ kuro niwaju Oluwa.
O si di ọjọ kan, nigbati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati obinrin njẹ, ti nwọn nmu ọti-waini ninu ile ẹgbọn wọn ọkunrin:
Onṣẹ kan si tọ̀ Jobu wá wipe: awọn ọda-malu ntulẹ, awọn kẹtẹkẹtẹ si njẹ li ẹba wọn;
Awọn ara Saba si kọlu wọn, nwọn si nkó wọn lọ, pẹlupẹlu nwọn ti fi idà ṣá awọn iranṣẹ pa, emi nikanṣoṣo li o sa asalà lati ròhin fun ọ.
Bi o ti nsọ li ẹnu; ẹnikan de pẹlu ti o si wipe: iná nla Ọlọrun ti ọrun bọ́ si ilẹ, o si jó awọn agutan ati awọn iranṣẹ ni ajorun; emi nikanṣoṣo li o salà lati rohin fun ọ.
Bi o si ti nsọ li ẹnu, ẹnikan si de pẹlu ti o wipe: awọn ara Kaldea pingun si ọ̀na mẹta, nwọn si kọlu awọn ibakasiẹ, nwọn si kó wọn lọ, pẹlupẹlu nwọn si fi idà ṣá awọn iranṣẹ pa; emi nikanṣoṣo li o sa asalà lati rohin fun ọ.
Bi o ti nsọ li ẹnu, ẹnikan de pẹlu ti o si wipe: awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati ọmọ rẹ obinrin njẹ nwọn nmu ọti-waini ninu ile ẹgbọn wọn ọkunrin.
Si kiyesi i, ẹfufu nlanla ti iha ijù fẹ wá ikọlu igun mẹrẹrin ile, o si wolù awọn ọdọmọkunrin na, nwọn si kú, emi nikanṣoṣo li o yọ lati rohin fun ọ.
Nigbana ni Jobu dide, o si fa aṣọ igunwa rẹ̀ ya, o si fari rẹ̀, o wolẹ, o si gbadura.
Wipe, Nihoho ni mo ti inu iya mi jade wá, nihoho ni emi o si tun pada lọ sibẹ: Oluwa fifunni Oluwa si gbà lọ, ibukun li orukọ Oluwa.
Ninu gbogbo eyi Jobu kò ṣẹ̀, bẹ̃ni kò si fi were pè Ọlọrun lẹjọ.