Nitorina awọn Ju kò gbagbọ́ nitori rẹ̀ pe, oju rẹ̀ ti fọ́ ri, ati pe o si tún riran, titi nwọn fi pe awọn obi ẹniti a ti là loju. Nwọn si bi wọn lẽre, wipe, Eyi li ọmọ nyin, ẹniti ẹnyin wipe, a bí i li afọju? ẽhaṣe ti o riran nisisiyi? Awọn obi rẹ̀ da wọn lohùn wipe, Awa mọ̀ pe ọmọ wa li eyi, ati pe a bí i li afọju: Ṣugbọn bi o ti ṣe nriran nisisiyi awa kò mọ̀; tabi ẹniti o la a loju, awa kò mọ̀: ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre: yio wi fun ara rẹ̀. Nkan wọnyi li awọn obi rẹ̀ sọ, nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn Ju: nitori awọn Ju ti fi ohùn ṣọkan pe, bi ẹnikan ba jẹwọ pe, Kristi ni iṣe, nwọn ó yọ ọ kuro ninu sinagogu. Nitori eyi li awọn obi rẹ̀ fi wipe, Ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre.
Kà Joh 9
Feti si Joh 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 9:18-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò