BI o si ti nkọja lọ, o ri ọkunrin kan ti o fọju lati igba ibí rẹ̀ wá. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe. Olukọni, tani dẹṣẹ, ọkunrin yi tabi awọn obi rẹ̀, ti a fi bi i li afọju? Jesu dahùn pe, Kì iṣe nitoriti ọkunrin yi dẹṣẹ, tabi awọn obi rẹ̀: ṣugbọn ki a le fi iṣẹ Ọlọrun hàn lara rẹ̀. Emi kò le ṣe alaiṣe iṣẹ ẹniti o rán mi, nigbati iṣe ọsan: oru mbọ̀ wá nigbati ẹnikan kì o le ṣe iṣẹ. Niwọn igba ti mo wà li aiye, emi ni imọlẹ aiye. Nigbati o ti wi bẹ̃ tan, o tutọ́ silẹ, o si fi itọ́ na ṣe amọ̀, o si fi amọ̀ na pa oju afọju na, O si wi fun u pe, Lọ, wẹ̀ ninu adagun Siloamu, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Ránlọ.) Nitorina o gbà ọ̀na rẹ̀ lọ, o wẹ̀, o si de, o nriran.
Kà Joh 9
Feti si Joh 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 9:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò