Ti eṣu baba nyin li ẹnyin iṣe, ifẹkufẹ baba nyin li ẹ si nfẹ ṣe. Apania li on iṣe lati atetekọṣe, ko si duro ni otitọ; nitoriti kò si otitọ ninu rẹ̀. Nigbati o ba nṣeke, ninu ohun tirẹ̀ li o nsọ, nitori eke ni, ati baba eke. Ṣugbọn nitori emi sọ otitọ fun nyin, ẹ kò si gbà mi gbọ́. Tani ninu nyin ti o ti idá mi li ẹbi ẹ̀ṣẹ? Bi mo ba nsọ otitọ ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà mi gbọ́? Ẹniti iṣe ti Ọlọrun, a ma gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun: nitori eyi li ẹnyin kò ṣe gbọ, nitori ẹnyin kì iṣe ti Ọlọrun.
Kà Joh 8
Feti si Joh 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 8:44-47
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò