Njẹ bi Jesu ti gbé oju rẹ̀ soke, ti o si ri ọ̀pọ enia wá sọdọ rẹ̀, o wi fun Filippi pe, Nibo li a o ti rà akara, ki awọn wọnyi le jẹ? O si sọ eyi lati dán a wò; nitoriti on tikararẹ̀ mọ̀ ohun ti on ó ṣe. Filippi da a lohùn pe, Akara igba owo idẹ ko to fun wọn, ti olukuluku wọn iba fi mu diẹ-diẹ. Ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Anderu, arakunrin Simoni Peteru wi fun u pe, Ọmọdekunrin kan mbẹ nihinyi, ti o ni iṣu akara barle marun, ati ẹja kékèké meji: ṣugbọn kini wọnyi jẹ lãrin ọ̀pọ enia wọnyi bi eyi? Jesu si wipe, Ẹ mu ki awọn enia na joko. Koriko pipọ si wà nibẹ̀. Bẹ̃li awọn ọkunrin na joko, ìwọn ẹgbẹdọgbọn enia ni iye. Jesu si mu iṣu akara wọnni; nigbati o si ti dupẹ, o pin wọn fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si pín wọn fun awọn ti o joko; bẹ̃ gẹgẹ si li ẹja ni ìwọn bi nwọn ti nfẹ. Nigbati nwọn si yó, o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ kó ajẹkù ti o kù jọ, ki ohunkohun máṣe ṣegbé. Bẹ̃ni nwọn kó wọn jọ nwọn si fi ajẹkù ìṣu akara barle marun na kún agbọn mejila eyi ti o ṣikù, fun awọn ti o jẹun.
Kà Joh 6
Feti si Joh 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 6:5-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò