Joh 6:35-69

Joh 6:35-69 YBCV

Jesu wi fun wọn pe, Emi li onjẹ ìye: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ́, orungbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai. Sugbọn mo wi fun nyin pe, Ẹnyin ti ri mi, ẹ kò si gbagbọ́. Ohun gbogbo ti Baba fifun mi, yio tọ̀ mi wá; ẹniti o ba si tọ̀ mi wá, emi kì yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri. Nitori emi sọkalẹ lati ọrun wá, ki iṣe lati mã ṣe ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi. Eyi si ni ifẹ Baba ti o rán mi, pe ohun gbogbo ti o fifun mi, ki emi ki o máṣe sọ ọkan nù ninu wọn, ṣugbọn ki emi ki o le ji wọn dide nikẹhin ọjọ. Eyi si ni ifẹ ẹniti o rán mi, pe ẹnikẹni ti o ba rí Ọmọ, ti o ba si gbà a gbọ́, ki o le ni iye ainipẹkun: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ. Nigbana ni awọn Ju nkùn si i, nitoriti o wipe, Emi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá. Nwọn si wipe, Jesu ha kọ́ eyi, ọmọ Josefu, baba ati iya ẹniti awa mọ̀? Ẽtiṣe tí ó wipe, Emi ti ọrun sọkalẹ wá? Nitorina Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe kùn lãrin ara nyin. Kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ mi, bikoṣepe Baba ti o rán mi fà a: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ. A sá ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, A o si kọ́ gbogbo wọn lati ọdọ Ọlọrun wá. Nitorina ẹnikẹni ti o ba ti gbọ́, ti a si ti ọdọ Baba kọ́, on li o ntọ̀ mi wá. Koṣepe ẹnikan ti ri Baba bikoṣe ẹniti o ti ọdọ Ọlọrun wá, on li o ti ri Baba. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, o ni ìye ainipẹkun. Emi li onjẹ ìye. Awọn baba nyin jẹ manna li aginjù, nwọn si kú. Eyi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá, ki enia le mã jẹ ninu rẹ̀ ki o má si kú. Emi ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai: onjẹ na ti emi o si fifunni li ara mi, fun ìye araiye. Nitorina li awọn Ju ṣe mba ara wọn jiyàn, wipe, ọkunrin yi yio ti ṣe le fi ara rẹ̀ fun wa lati jẹ? Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe ẹnyin ba jẹ ara Ọmo-enia, ki ẹnyin si mu ẹ̀jẹ rẹ̀, ẹnyin kò ni ìye ninu nyin. Ẹnikẹni ti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ni ìye ti kò nipẹkun; Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ. Nitori ara mi li ohun jijẹ nitõtọ, ati ẹ̀jẹ mi li ohun mimu nitõtọ. Ẹniti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ngbé inu mi, emi si ngbé inu rẹ̀. Gẹgẹ bi Baba alãye ti rán mi, ti emi si ye nipa Baba: gẹgẹ bẹ̃li ẹniti o jẹ mi, on pẹlu yio yè nipa mi. Eyi si li onjẹ na ti o sọkalẹ lati ọrun wá: ki iṣe bi awọn baba nyin ti jẹ manna, ti nwọn si kú: ẹniti o ba jẹ onjẹ yi yio yè lailai. Nkan wọnyi li o sọ ninu sinagogu, bi o ti nkọni ni Kapernaumu. Nitorina nigbati ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọ̀rọ ti o le li eyi; tani le gbọ́ ọ? Nigbati Jesu si mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nkùn si ọ̀rọ na, o wi fun wọn pe, Eyi jẹ ikọsẹ̀ fun nyin bi? Njẹ, bi ẹnyin ba si ri ti Ọmọ-enia ngòke lọ sibi ti o gbé ti wà ri nkọ́? Ẹmí ni isọni di ãye; ara kò ni ère kan; ọ̀rọ wọnni ti mo sọ fun nyin, ẹmi ni, ìye si ni. Ṣugbọn awọn kan wà ninu nyin ti kò gbagbọ́. Nitori Jesu mọ̀ lati ìbẹrẹ wá ẹniti nwọn iṣe ti ko gbagbọ́, ati ẹniti yio fi on hàn. O si wipe, Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, kò si ẹniti o le tọ̀ mi wá, bikoṣepe a fifun u lati ọdọ Baba mi wá. Nitori eyi ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pada sẹhin, nwọn kò si bá a rìn mọ́. Nitorina Jesu wi fun awọn mejila pe, Ẹnyin pẹlu nfẹ lọ bi? Nigbana ni Simoni Peteru da a lohùn wipe, Oluwa, Ọdọ tali awa o lọ? Iwọ li o ni ọ̀rọ ìye ainipẹkun. Awa si ti gbagbọ́, a si mọ̀ pe, iwọ ni Kristi na, Ọmọ Ọlọrun alãye.

Verse Images for Joh 6:35-69

Joh 6:35-69 - Jesu wi fun wọn pe, Emi li onjẹ ìye: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ́, orungbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai.
Sugbọn mo wi fun nyin pe, Ẹnyin ti ri mi, ẹ kò si gbagbọ́.
Ohun gbogbo ti Baba fifun mi, yio tọ̀ mi wá; ẹniti o ba si tọ̀ mi wá, emi kì yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri.
Nitori emi sọkalẹ lati ọrun wá, ki iṣe lati mã ṣe ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi.
Eyi si ni ifẹ Baba ti o rán mi, pe ohun gbogbo ti o fifun mi, ki emi ki o máṣe sọ ọkan nù ninu wọn, ṣugbọn ki emi ki o le ji wọn dide nikẹhin ọjọ.
Eyi si ni ifẹ ẹniti o rán mi, pe ẹnikẹni ti o ba rí Ọmọ, ti o ba si gbà a gbọ́, ki o le ni iye ainipẹkun: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.
Nigbana ni awọn Ju nkùn si i, nitoriti o wipe, Emi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá.
Nwọn si wipe, Jesu ha kọ́ eyi, ọmọ Josefu, baba ati iya ẹniti awa mọ̀? Ẽtiṣe tí ó wipe, Emi ti ọrun sọkalẹ wá?
Nitorina Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe kùn lãrin ara nyin.
Kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ mi, bikoṣepe Baba ti o rán mi fà a: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.
A sá ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, A o si kọ́ gbogbo wọn lati ọdọ Ọlọrun wá. Nitorina ẹnikẹni ti o ba ti gbọ́, ti a si ti ọdọ Baba kọ́, on li o ntọ̀ mi wá.
Koṣepe ẹnikan ti ri Baba bikoṣe ẹniti o ti ọdọ Ọlọrun wá, on li o ti ri Baba.
Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, o ni ìye ainipẹkun.
Emi li onjẹ ìye.
Awọn baba nyin jẹ manna li aginjù, nwọn si kú.
Eyi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá, ki enia le mã jẹ ninu rẹ̀ ki o má si kú.
Emi ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai: onjẹ na ti emi o si fifunni li ara mi, fun ìye araiye.
Nitorina li awọn Ju ṣe mba ara wọn jiyàn, wipe, ọkunrin yi yio ti ṣe le fi ara rẹ̀ fun wa lati jẹ?
Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe ẹnyin ba jẹ ara Ọmo-enia, ki ẹnyin si mu ẹ̀jẹ rẹ̀, ẹnyin kò ni ìye ninu nyin.
Ẹnikẹni ti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ni ìye ti kò nipẹkun; Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.
Nitori ara mi li ohun jijẹ nitõtọ, ati ẹ̀jẹ mi li ohun mimu nitõtọ.
Ẹniti o ba jẹ ara mi, ti o ba si mu ẹ̀jẹ mi, o ngbé inu mi, emi si ngbé inu rẹ̀.
Gẹgẹ bi Baba alãye ti rán mi, ti emi si ye nipa Baba: gẹgẹ bẹ̃li ẹniti o jẹ mi, on pẹlu yio yè nipa mi.
Eyi si li onjẹ na ti o sọkalẹ lati ọrun wá: ki iṣe bi awọn baba nyin ti jẹ manna, ti nwọn si kú: ẹniti o ba jẹ onjẹ yi yio yè lailai.
Nkan wọnyi li o sọ ninu sinagogu, bi o ti nkọni ni Kapernaumu.

Nitorina nigbati ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọ̀rọ ti o le li eyi; tani le gbọ́ ọ?
Nigbati Jesu si mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nkùn si ọ̀rọ na, o wi fun wọn pe, Eyi jẹ ikọsẹ̀ fun nyin bi?
Njẹ, bi ẹnyin ba si ri ti Ọmọ-enia ngòke lọ sibi ti o gbé ti wà ri nkọ́?
Ẹmí ni isọni di ãye; ara kò ni ère kan; ọ̀rọ wọnni ti mo sọ fun nyin, ẹmi ni, ìye si ni.
Ṣugbọn awọn kan wà ninu nyin ti kò gbagbọ́. Nitori Jesu mọ̀ lati ìbẹrẹ wá ẹniti nwọn iṣe ti ko gbagbọ́, ati ẹniti yio fi on hàn.
O si wipe, Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, kò si ẹniti o le tọ̀ mi wá, bikoṣepe a fifun u lati ọdọ Baba mi wá.
Nitori eyi ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pada sẹhin, nwọn kò si bá a rìn mọ́.
Nitorina Jesu wi fun awọn mejila pe, Ẹnyin pẹlu nfẹ lọ bi?
Nigbana ni Simoni Peteru da a lohùn wipe, Oluwa, Ọdọ tali awa o lọ? Iwọ li o ni ọ̀rọ ìye ainipẹkun.
Awa si ti gbagbọ́, a si mọ̀ pe, iwọ ni Kristi na, Ọmọ Ọlọrun alãye.Joh 6:35-69 - Jesu wi fun wọn pe, Emi li onjẹ ìye: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ́, orungbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai.

Awa si ti gbagbọ́, a si mọ̀ pe, iwọ ni Kristi na, Ọmọ Ọlọrun alãye.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa