Ni ijọ keji, nigbati awọn enia ti o duro li apakeji okun ri pe, kò si ọkọ̀ miran nibẹ̀, bikoṣe ọkanna ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀, ati pe Jesu kò ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀ inu ọkọ̀ na, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nikan li o lọ;
(Ṣugbọn awọn ọkọ̀ miran ti Tiberia wá, leti ibi ti nwọn gbe jẹ akara, lẹhin igbati Oluwa ti dupẹ:)
Nitorina nigbati awọn enia ri pe, Jesu kò si nibẹ̀, tabi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn pẹlu wọ̀ ọkọ̀ lọ si Kapernaumu, nwọn nwá Jesu.
Nigbati nwọn si ri i li apakeji okun nwọn wi fun u pe, Rabbi, nigbawo ni iwọ wá sihinyi?
Jesu da wọn lohùn o si wipe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnyin nwá mi, ki iṣe nitoriti ẹnyin ri iṣẹ àmi, ṣugbọn nitori ẹnyin jẹ iṣu akara wọnni, ẹnyin si yó.
Ẹ máṣe ṣiṣẹ fun onjẹ ti iṣegbé, ṣugbọn fun onjẹ ti iwà ti di ìye ainipẹkun, eyiti Ọmọ-enia yio fifun nyin: nitoripe on ni, ani Ọlọrun Baba ti fi edidi dí.
Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Kili awa o ha ṣe, ki a le ṣe iṣẹ Ọlọrun?
Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Eyi ni iṣẹ Ọlọrun pe, ki ẹnyin ki o gbà ẹniti o rán gbọ́.
Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iṣẹ ami kini iwọ nṣe, ki awa le ri, ki a si gbà ọ gbọ́? Iṣẹ kini iwọ ṣe?
Awọn baba wa jẹ manna li aginjù; gẹgẹ bi a ti kọ ọ́ pe, O fi onjẹ fun wọn jẹ lati ọrun wá.
Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, kì iṣe Mose li o fi onjẹ nì fun nyin lati ọrun wá; ṣugbọn Baba mi li o fi onjẹ otitọ nì fun nyin lati ọrun wá.
Nitoripe onjẹ Ọlọrun li ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ti o si fi ìye fun araiye.
Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Oluwa, mã fun wa li onjẹ yi titi lai.
Jesu wi fun wọn pe, Emi li onjẹ ìye: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ́, orungbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai.
Sugbọn mo wi fun nyin pe, Ẹnyin ti ri mi, ẹ kò si gbagbọ́.
Ohun gbogbo ti Baba fifun mi, yio tọ̀ mi wá; ẹniti o ba si tọ̀ mi wá, emi kì yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri.
Nitori emi sọkalẹ lati ọrun wá, ki iṣe lati mã ṣe ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi.
Eyi si ni ifẹ Baba ti o rán mi, pe ohun gbogbo ti o fifun mi, ki emi ki o máṣe sọ ọkan nù ninu wọn, ṣugbọn ki emi ki o le ji wọn dide nikẹhin ọjọ.
Eyi si ni ifẹ ẹniti o rán mi, pe ẹnikẹni ti o ba rí Ọmọ, ti o ba si gbà a gbọ́, ki o le ni iye ainipẹkun: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.