Ati Baba ti o rán mi ti jẹri mi. Ẹnyin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nigba kan ri, bẹ̃li ẹ kò ri àwọ rẹ̀. Ẹ kò si ni ọ̀rọ rẹ̀ lati ma gbé inu nyin: nitori ẹniti o rán, on li ẹnyin kò gbagbọ́. Ẹnyin nwá inu iwe-mimọ́ nitori ẹnyin rò pe ninu wọn li ẹnyin ni ìye ti kò nipẹkun; wọnyi si li awọn ti njẹri mi. Ẹnyin kò si fẹ lati wá sọdọ mi, ki ẹnyin ki o le ni ìye. Emi kò gbà ogo lọdọ enia. Ṣugbọn emi mọ̀ nyin pe, ẹnyin tikaranyin kò ni ifẹ Ọlọrun ninu nyin. Emi wá li orukọ Baba mi, ẹnyin kò si gbà mi: bi ẹlomiran ba wá li orukọ ara rẹ̀, on li ẹnyin ó gbà. Ẹnyin o ti ṣe le gbagbọ́, ẹnyin ti ngbà ogo lọdọ ara nyin, ti kò wá ogo ti o ti ọdọ Ọlọrun nikan wá? Ẹ máṣe rò pe, emi ó fi nyin sùn lọdọ Baba: ẹniti nfi nyin sùn wà, ani Mose, ẹniti ẹnyin gbẹkẹle. Nitoripe ẹnyin iba gbà Mose gbọ́, ẹnyin iba gbà mi gbọ́: nitori o kọ iwe nipa ti emi. Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbà iwe rẹ̀ gbọ́, ẹnyin o ti ṣe gbà ọ̀rọ mi gbọ́?
Kà Joh 5
Feti si Joh 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 5:37-47
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò