Joh 5:30-47

Joh 5:30-47 YBCV

Emi kò le ṣe ohun kan fun ara mi: bi mo ti ngbọ́, mo ndajọ: ododo si ni idajọ mi; nitori emi kò wá ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi. Bi emi ba njẹri ara mi, ẹrí mi kì iṣe otitọ. Ẹlomiran li ẹniti njẹri mi; emi si mọ̀ pe, otitọ li ẹrí mi ti o jẹ́. Ẹnyin ti ranṣẹ lọ sọdọ Johanu, on si ti jẹri si otitọ. Ṣugbọn emi kò gba ẹrí lọdọ enia: ṣugbọn nkan wọnyi li emi nsọ, ki ẹnyin ki o le là. On ni fitila ti o njó, ti o si ntànmọlẹ: ẹnyin si fẹ fun sã kan lati mã yọ̀ ninu imọlẹ rẹ̀. Ṣugbọn emi ni ẹri ti o pọ̀ju ti Johanu lọ: nitori iṣẹ ti Baba ti fifun mi lati ṣe pari, iṣẹ na pãpã ti emi nṣe ni njẹri mi pe, Baba li o rán mi. Ati Baba ti o rán mi ti jẹri mi. Ẹnyin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nigba kan ri, bẹ̃li ẹ kò ri àwọ rẹ̀. Ẹ kò si ni ọ̀rọ rẹ̀ lati ma gbé inu nyin: nitori ẹniti o rán, on li ẹnyin kò gbagbọ́. Ẹnyin nwá inu iwe-mimọ́ nitori ẹnyin rò pe ninu wọn li ẹnyin ni ìye ti kò nipẹkun; wọnyi si li awọn ti njẹri mi. Ẹnyin kò si fẹ lati wá sọdọ mi, ki ẹnyin ki o le ni ìye. Emi kò gbà ogo lọdọ enia. Ṣugbọn emi mọ̀ nyin pe, ẹnyin tikaranyin kò ni ifẹ Ọlọrun ninu nyin. Emi wá li orukọ Baba mi, ẹnyin kò si gbà mi: bi ẹlomiran ba wá li orukọ ara rẹ̀, on li ẹnyin ó gbà. Ẹnyin o ti ṣe le gbagbọ́, ẹnyin ti ngbà ogo lọdọ ara nyin, ti kò wá ogo ti o ti ọdọ Ọlọrun nikan wá? Ẹ máṣe rò pe, emi ó fi nyin sùn lọdọ Baba: ẹniti nfi nyin sùn wà, ani Mose, ẹniti ẹnyin gbẹkẹle. Nitoripe ẹnyin iba gbà Mose gbọ́, ẹnyin iba gbà mi gbọ́: nitori o kọ iwe nipa ti emi. Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbà iwe rẹ̀ gbọ́, ẹnyin o ti ṣe gbà ọ̀rọ mi gbọ́?

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joh 5:30-47