Joh 5:1-29

Joh 5:1-29 YBCV

LẸHIN nkan wọnyi ajọ awọn Ju kan kò; Jesu si gòke lọ si Jerusalemu. Adagun omi kan si wà ni Jerusalemu, leti bodè agutan, ti a npè ni Betesda li ède Heberu, ti o ni iloro marun. Ninu wọnyi li ọ̀pọ awọn abirùn enia gbé dubulẹ si, awọn afọju, arọ ati awọn gbigbẹ, nwọn si nduro dè rirú omi. Nitori angẹli a ma digbà sọkalẹ lọ sinu adagun na, a si ma rú omi: lẹhin igbati a ba ti rú omi na tan ẹnikẹni ti o ba kọ́ wọ̀ inu rẹ̀, a di alaradidá ninu arùnkárun ti o ni. Ọkunrin kan si wà nibẹ̀, ẹniti o wà ni ailera rẹ̀ li ọdún mejidilogoji. Bi Jesu ti ri i ni idubulẹ, ti o si mọ̀ pe, o pẹ ti o ti wà bẹ̃, o wi fun u pe, Iwọ fẹ ki a mu ọ larada bi? Abirùn na da a lohùn wipe, Ọgbẹni, emi kò li ẹni, ti iba gbé mi sinu adagun, nigbati a ba nrú omi na: bi emi ba ti mbọ̀ wá, ẹlomiran a sọkalẹ sinu rẹ̀ ṣiwaju mi. Jesu wi fun u pe, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã rin. Lọgan a si mu ọkunrin na larada, o si gbé akete rẹ̀, o si nrìn. Ọjọ na si jẹ ọjọ isimi. Nitorina awọn Ju wi fun ọkunrin na ti a mu larada pe, Ọjọ isimi li oni: kò tọ́ fun ọ lati gbé akete rẹ. O si da wọn lohùn wipe, Ẹniti o mu mi larada, on li o wi fun mi pe, Gbé akete rẹ, ki o si mã rìn. Nigbana ni nwọn bi i lẽre wipe, Ọkunrin wo li ẹniti o wi fun ọ pe, Gbé akete rẹ, ki o si mã rìn? Ẹniti a mu larada nã kò si mọ̀ ẹniti iṣe: nitori Jesu ti kuro nibẹ̀, nitori awọn enia pipọ wà nibẹ̀. Lẹhinna Jesu ri i ni tẹmpili o si wi fun u pe, Wo o, a mu ọ larada: máṣe dẹṣẹ mọ́, ki ohun ti o buru jù yi lọ ki o má bà ba ọ. Ọkunrin na lọ, o si sọ fun awọn Ju pe, Jesu li ẹniti o mu on larada. Nitori eyi li awọn Ju si nṣe inunibini si Jesu, nwọn si nwá ọ̀na ati pa a, nitoriti a nṣe nkan wọnyi li ọjọ isimi. Ṣugbọn Jesu da wọn lohùn wipe, Baba mi nṣiṣẹ titi di isisiyi, emi si nṣiṣẹ. Nitori eyi li awọn Ju tubọ nwá ọ̀na ati pa a, ki iṣe nitoripe o ba ọjọ isimi jẹ nikan ni, ṣugbọn o wi pẹlu pe, Baba on li Ọlọrun iṣe, o nmu ara rẹ̀ ba Ọlọrun dọgba. Nigbana ni Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọmọ kò le ṣe ohunkohun fun ara rẹ̀, bikoṣe ohun ti o ba ri pe Baba nṣe: nitori ohunkohun ti o ba nṣe, wọnyi li Ọmọ si nṣe bẹ̃ gẹgẹ. Nitori Baba fẹràn Ọmọ, o si fi ohun gbogbo ti on tikararẹ̀ nṣe hàn a: on ó si fi iṣẹ ti o tobi ju wọnyi lọ hàn a, ki ẹnu ki o le yà nyin. Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti njí okú dide, ti o si nsọ wọn di ãye; bẹ̃li Ọmọ si nsọ awọn ti o fẹ di ãye. Nitoripe Baba ki iṣe idajọ ẹnikẹni, ṣugbọn o ti fi gbogbo idajọ le Ọmọ lọwọ: Ki gbogbo enia ki o le mã fi ọlá fun Ọmọ gẹgẹ bi nwọn ti nfi ọlá fun Baba. Ẹniti kò ba fi ọlá fun Ọmọ, kò fi ọlá fun Baba ti o rán a. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ̀rọ mi, ti o ba si gbà ẹniti o rán mi gbọ́, o ni iye ti kò nipẹkun, on kì yio si wá si idajọ; ṣugbọn o ti ré ikú kọja bọ si ìye. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Wakati na mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn okú yio gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọrun: awọn ti o ba gbọ yio si yè. Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti ni iye ninu ara rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃li o si fifun Ọmọ lati ni iye ninu ara rẹ̀; O si fun u li aṣẹ lati mã ṣe idajọ pẹlu, nitoriti on iṣe Ọmọ-enia. Ki eyi ki o máṣe yà nyin li ẹnu; nitoripe wakati mbọ̀, ninu eyiti gbogbo awọn ti o wà ni isà okú yio gbọ́ ohùn rẹ̀. Nwọn o si jade wá; awọn ti o ṣe rere, si ajinde ìye; awọn ti o si ṣe buburu, si ajinde idajọ.

Àwọn fídíò fún Joh 5:1-29