Joh 4:7-29

Joh 4:7-29 YBCV

Obinrin kan, ara Samaria, si wá lati pọn omi: Jesu wi fun u pe, Fun mi mu. (Nitori awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ti lọ si ilu lọ irà onjẹ.) Nigbana li obinrin ara Samaria na wi fun u pe, Ẽti ri ti iwọ ti iṣe Ju, fi mbère ohun mimu lọwọ mi, emi ẹniti iṣe obinrin ara Samaria? nitoriti awọn Ju ki iba awọn ara Samaria da nkan pọ̀. Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ibaṣepe iwọ mọ̀ ẹ̀bun Ọlọrun, ati ẹniti o wi fun ọ pe, Fun mi mu, iwọ iba si ti bère lọwọ rẹ̀, on iba ti fi omi ìye fun ọ. Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, iwọ kò ni nkan ti iwọ o fi fà omi, bẹ̃ni kanga na jìn: nibo ni iwọ gbé ti ri omi ìye na? Iwọ pọ̀ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹniti o fun wa ni kanga na, ti on tikararẹ̀ mu ninu rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ẹran rẹ̀? Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi yi, orùngbẹ yio si tún gbẹ ẹ: Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orùngbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rẹ̀, ti yio ma sun si ìye ainipẹkun. Obinrin na si wi fun u pe, Ọgbẹni, fun mi li omi yi, ki orùngbẹ ki o màṣe gbẹ mi, ki emi ki o má si wá fà omi nihin. Jesu wi fun u pe, Lọ ipè ọkọ rẹ, ki o si wá si ihinyi. Obinrin na dahùn, o si wi fun u pe, Emi kò li ọkọ. Jesu wi fun u pe, Iwọ wi rere pe, emi kò li ọkọ: Nitoriti iwọ ti li ọkọ marun ri; ẹniti iwọ si ni nisisiyi kì iṣe ọkọ rẹ; iwọ sọ otitọ li eyini. Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, mo woye pe, woli ni iwọ iṣe. Awọn baba wa sìn lori òke yi; ẹnyin si wipe, Jerusalemu ni ibi ti o yẹ ti a ba ma sìn. Jesu wi fun u pe, Gbà mi gbọ́, obinrin yi, wakati na mbọ̀, nigbati kì yio ṣe lori òke yi, tabi Jerusalemu, li ẹnyin o ma sìn Baba. Ẹnyin nsìn ohun ti ẹnyin kò mọ̀: awa nsìn ohun ti awa mọ̀: nitori igbala ti ọdọ awọn Ju wá. Ṣugbọn wakati mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin tõtọ yio ma sìn Baba li ẹmí ati li otitọ: nitori irú wọn ni Baba nwá ki o ma sìn on. Ẹmí li Ọlọrun: awọn ẹniti nsìn i ko le ṣe alaisìn i li ẹmí ati li otitọ. Obinrin na wi fun u pe, Mo mọ̀ pe Messia mbọ̀ wá, ti a npè ni Kristi: nigbati on ba de, yio sọ ohun gbogbo fun wa. Jesu wi fun u pe, Emi ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi li on. Lori eyi li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ de, ẹnu si yà wọn, pe o mba obinrin sọ̀rọ: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o wipe, Kini iwọ nwá? tabi, Ẽṣe ti iwọ fi mba a sọ̀rọ? Nigbana li obinrin na fi ladugbo rẹ̀ silẹ, o si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n lọ si ilu, o si wi fun awọn enia pe, Ẹ wá wò ọkunrin kan, ẹniti o sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe ri fun mi: eyi ha le jẹ Kristi na?

Verse Images for Joh 4:7-29

Joh 4:7-29 - Obinrin kan, ara Samaria, si wá lati pọn omi: Jesu wi fun u pe, Fun mi mu.
(Nitori awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ti lọ si ilu lọ irà onjẹ.)
Nigbana li obinrin ara Samaria na wi fun u pe, Ẽti ri ti iwọ ti iṣe Ju, fi mbère ohun mimu lọwọ mi, emi ẹniti iṣe obinrin ara Samaria? nitoriti awọn Ju ki iba awọn ara Samaria da nkan pọ̀.
Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ibaṣepe iwọ mọ̀ ẹ̀bun Ọlọrun, ati ẹniti o wi fun ọ pe, Fun mi mu, iwọ iba si ti bère lọwọ rẹ̀, on iba ti fi omi ìye fun ọ.
Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, iwọ kò ni nkan ti iwọ o fi fà omi, bẹ̃ni kanga na jìn: nibo ni iwọ gbé ti ri omi ìye na?
Iwọ pọ̀ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹniti o fun wa ni kanga na, ti on tikararẹ̀ mu ninu rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ẹran rẹ̀?
Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi yi, orùngbẹ yio si tún gbẹ ẹ:
Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orùngbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rẹ̀, ti yio ma sun si ìye ainipẹkun.
Obinrin na si wi fun u pe, Ọgbẹni, fun mi li omi yi, ki orùngbẹ ki o màṣe gbẹ mi, ki emi ki o má si wá fà omi nihin.
Jesu wi fun u pe, Lọ ipè ọkọ rẹ, ki o si wá si ihinyi.
Obinrin na dahùn, o si wi fun u pe, Emi kò li ọkọ. Jesu wi fun u pe, Iwọ wi rere pe, emi kò li ọkọ:
Nitoriti iwọ ti li ọkọ marun ri; ẹniti iwọ si ni nisisiyi kì iṣe ọkọ rẹ; iwọ sọ otitọ li eyini.
Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, mo woye pe, woli ni iwọ iṣe.
Awọn baba wa sìn lori òke yi; ẹnyin si wipe, Jerusalemu ni ibi ti o yẹ ti a ba ma sìn.
Jesu wi fun u pe, Gbà mi gbọ́, obinrin yi, wakati na mbọ̀, nigbati kì yio ṣe lori òke yi, tabi Jerusalemu, li ẹnyin o ma sìn Baba.
Ẹnyin nsìn ohun ti ẹnyin kò mọ̀: awa nsìn ohun ti awa mọ̀: nitori igbala ti ọdọ awọn Ju wá.
Ṣugbọn wakati mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin tõtọ yio ma sìn Baba li ẹmí ati li otitọ: nitori irú wọn ni Baba nwá ki o ma sìn on.
Ẹmí li Ọlọrun: awọn ẹniti nsìn i ko le ṣe alaisìn i li ẹmí ati li otitọ.
Obinrin na wi fun u pe, Mo mọ̀ pe Messia mbọ̀ wá, ti a npè ni Kristi: nigbati on ba de, yio sọ ohun gbogbo fun wa.
Jesu wi fun u pe, Emi ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi li on.
Lori eyi li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ de, ẹnu si yà wọn, pe o mba obinrin sọ̀rọ: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o wipe, Kini iwọ nwá? tabi, Ẽṣe ti iwọ fi mba a sọ̀rọ?
Nigbana li obinrin na fi ladugbo rẹ̀ silẹ, o si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n lọ si ilu, o si wi fun awọn enia pe,
Ẹ wá wò ọkunrin kan, ẹniti o sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe ri fun mi: eyi ha le jẹ Kristi na?

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joh 4:7-29