Lãrin eyi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nrọ̀ ọ, wipe, Rabbi, jẹun. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Emi li onjẹ lati jẹ, ti ẹnyin kò mọ̀. Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mbi ara wọn lère wipe, Ẹnikan mú onjẹ fun u wá lati jẹ bi? Jesu wi fun wọn pe, Onjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹniti o rán mi, ati lati pari iṣẹ rẹ̀. Ẹnyin kò ha nwipe, O kù oṣù mẹrin, ikorè yio si de? wo o, mo wi fun nyin, Ẹ gbé oju nyin soke, ki ẹ si wó oko; nitoriti nwọn ti funfun fun ikore na. Ẹniti nkorè ngba owo ọ̀ya, o si nkó eso jọ si ìye ainipẹkun: ki ẹniti o nfunrugbin ati ẹniti nkore le jọ mã yọ̀ pọ̀. Nitori ninu eyi ni ọ̀rọ na fi jẹ otitọ: Ẹnikan li o fọnrugbin, ẹlomiran li o si nkòre jọ. Mo rán nyin lọ ikore ohun ti ẹ kò ṣiṣẹ le lori: awọn ẹlomiran ti ṣiṣẹ, ẹnyin si wọ̀ inu iṣẹ wọn lọ.
Kà Joh 4
Feti si Joh 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 4:31-38
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò