Joh 4:27-42

Joh 4:27-42 YBCV

Lori eyi li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ de, ẹnu si yà wọn, pe o mba obinrin sọ̀rọ: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o wipe, Kini iwọ nwá? tabi, Ẽṣe ti iwọ fi mba a sọ̀rọ? Nigbana li obinrin na fi ladugbo rẹ̀ silẹ, o si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n lọ si ilu, o si wi fun awọn enia pe, Ẹ wá wò ọkunrin kan, ẹniti o sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe ri fun mi: eyi ha le jẹ Kristi na? Nigbana ni nwọn ti ilu jade, nwọn si tọ̀ ọ wá. Lãrin eyi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nrọ̀ ọ, wipe, Rabbi, jẹun. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Emi li onjẹ lati jẹ, ti ẹnyin kò mọ̀. Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mbi ara wọn lère wipe, Ẹnikan mú onjẹ fun u wá lati jẹ bi? Jesu wi fun wọn pe, Onjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹniti o rán mi, ati lati pari iṣẹ rẹ̀. Ẹnyin kò ha nwipe, O kù oṣù mẹrin, ikorè yio si de? wo o, mo wi fun nyin, Ẹ gbé oju nyin soke, ki ẹ si wó oko; nitoriti nwọn ti funfun fun ikore na. Ẹniti nkorè ngba owo ọ̀ya, o si nkó eso jọ si ìye ainipẹkun: ki ẹniti o nfunrugbin ati ẹniti nkore le jọ mã yọ̀ pọ̀. Nitori ninu eyi ni ọ̀rọ na fi jẹ otitọ: Ẹnikan li o fọnrugbin, ẹlomiran li o si nkòre jọ. Mo rán nyin lọ ikore ohun ti ẹ kò ṣiṣẹ le lori: awọn ẹlomiran ti ṣiṣẹ, ẹnyin si wọ̀ inu iṣẹ wọn lọ. Ọpọ awọn ara Samaria lati ilu na wá si gbà a gbọ́, nitori ọ̀rọ obinrin na, o jẹri pe, O sọ gbogbo ohun ti mo ti ṣe fun mi. Nitorina, nigbati awọn ara Samaria wá sọdọ rẹ̀, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o ba wọn joko: o si gbé ibẹ̀ ni ijọ meji. Awọn ọ̀pọlọpọ si i si gbagbọ́ nitori ọ̀rọ rẹ̀; Nwọn si wi fun obinrin na pe, Ki iṣe nitori ọrọ rẹ mọ li awa ṣe gbagbọ: nitoriti awa tikarawa ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, awa si mọ̀ pe, nitõtọ eyi ni Kristi na, Olugbala araiye.

Video for Joh 4:27-42

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joh 4:27-42