Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, nigbati iwọ wà li ọdọmọde, iwọ a ma di ara rẹ li àmurè, iwọ a si ma rìn lọ si ibiti iwọ ba fẹ: ṣugbọn nigbati iwọ ba di arugbo, iwọ o nà ọwọ́ rẹ jade, ẹlomiran yio si di ọ li amure, yio si mu ọ lọ si ibiti iwọ kò fẹ. O wi eyi, o fi nṣapẹrẹ irú ikú ti yio fi yìn Ọlọrun logo. Lẹhin igbati o si ti wi eyi tan, o wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. Peteru si yipada, o ri ọmọ-ẹhin nì, ẹniti Jesu fẹràn, mbọ̀ lẹhin; ẹniti o si rọ̀gun si àiya rẹ̀ nigba onjẹ alẹ ti o si wi fun u pe, Oluwa, tali ẹniti yõ fi ọ hàn? Nigbati Peteru ri i, o wi fun Jesu pe, Oluwa, Eleyi ha nkọ́? Jesu wi fun u pe, Bi emi ba fẹ ki o duro titi emi o fi de, kili eyini si ọ? Ìwọ mã tọ̀ mi lẹhin.
Kà Joh 21
Feti si Joh 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 21:18-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò