Njẹ lẹhin igbati nwọn jẹun owurọ̀ tan, Jesu wi fun Simoni Peteru pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi jù awọn wọnyi lọ bi? O si wi fun u pe, Bẹ̃ni Oluwa; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. O wi fun u pe, Mã bọ́ awọn ọdọ-agutan mi.
O tún wi fun u nigba keji pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi bi? O wi fun u pe, Bẹ̃ni Oluwa; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. O wi fun u pe, Mã bọ́ awọn agutan mi.
O wi fun u nigba kẹta pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹràn mi bi? Inu Peteru bajẹ, nitoriti o wi fun u nigba ẹkẹta pe, Iwọ fẹràn mi bi? O si wi fun u pe, Oluwa, iwọ mọ̀ ohun gbogbo; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. Jesu wi fun u pe, Mã bọ́ awọn agutan mi.
Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, nigbati iwọ wà li ọdọmọde, iwọ a ma di ara rẹ li àmurè, iwọ a si ma rìn lọ si ibiti iwọ ba fẹ: ṣugbọn nigbati iwọ ba di arugbo, iwọ o nà ọwọ́ rẹ jade, ẹlomiran yio si di ọ li amure, yio si mu ọ lọ si ibiti iwọ kò fẹ.
O wi eyi, o fi nṣapẹrẹ irú ikú ti yio fi yìn Ọlọrun logo. Lẹhin igbati o si ti wi eyi tan, o wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin.
Peteru si yipada, o ri ọmọ-ẹhin nì, ẹniti Jesu fẹràn, mbọ̀ lẹhin; ẹniti o si rọ̀gun si àiya rẹ̀ nigba onjẹ alẹ ti o si wi fun u pe, Oluwa, tali ẹniti yõ fi ọ hàn?
Nigbati Peteru ri i, o wi fun Jesu pe, Oluwa, Eleyi ha nkọ́?
Jesu wi fun u pe, Bi emi ba fẹ ki o duro titi emi o fi de, kili eyini si ọ? Ìwọ mã tọ̀ mi lẹhin.
Nitorina ọ̀rọ yi si tàn ka lãrin awọn arakunrin pe, ọmọ-ẹhin nì kì yio kú: ṣugbọn Jesu kò wi fun u pe, On kì yio kú; ṣugbọn, Bi emi ba fẹ ki o duro titi emi o fi de, kili eyinì si ọ?
Eyi li ọmọ-ẹhin na, ti o jẹri nkan wọnyi, ti o si kọwe nkan wọnyi: awa si mọ̀ pe, otitọ ni ẹ̀rí rẹ̀.
Ọpọlọpọ ohun miran pẹlu ni Jesu ṣe, eyiti bi a ba kọwe wọn li ọkọ̃kan, mo rò pe aiye pãpã kò le gbà iwe na ti a ba kọ. Amin.