Lẹhin ijọ mẹjọ awọn ọmọ-ẹhin si tún wà ninu ile, ati Tomasi pẹlu wọn: nigbati a si ti tì ilẹkun, Jesu de, o si duro larin, o si wipe, Alafia fun nyin. Nigbana li o wi fun Tomasi pe, Mu ika rẹ wá nihin, ki o si wò ọwọ́ mi; si mu ọwọ́ rẹ wá nihin, ki o si fi si ìha mi: kì iwọ ki o máṣe alaigbagbọ́ mọ́, ṣugbọn jẹ onigbagbọ. Tomasi dahun o si wi fun u pe, Oluwa mi ati Ọlọrun mi! Jesu wi fun u pe, Nitoriti iwọ ri mi ni iwọ ṣe gbagbọ́: alabukun-fun li awọn ti kò ri, ti nwọn si gbagbọ́. Ọpọlọpọ iṣẹ àmi miran ni Jesu ṣe niwaju awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ti a kò kọ sinu iwe yi: Ṣugbọn wọnyi li a kọ, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́ pe, Jesu ni iṣe Kristi na, Ọmọ Ọlọrun; ati ni gbigbàgbọ́, ki ẹnyin ki o le ni ìye li orukọ rẹ̀.
Kà Joh 20
Feti si Joh 20
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 20:26-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò