NI ijọ kẹta a si nṣe igbeyawo kan ni Kana ti Galili; iya Jesu si mbẹ nibẹ̀: A si pè Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pẹlu, si ibi igbeyawo. Nigbati waini si tan, iya Jesu wi fun u pe, Nwọn kò ni waini. Jesu wi fun u pe, Kini ṣe temi tirẹ, obinrin yi? wakati mi kò iti de. Iya rẹ̀ wi fun awọn iranṣẹ pe, Ohunkohun ti o ba wi fun nyin, ẹ ṣe e. Ikoko okuta omi mẹfa li a si gbé kalẹ nibẹ̀, gẹgẹ bi iṣe ìwẹnu awọn Ju, ọkọkan nwọn gbà to ìwọn ládugbó meji tabi mẹta. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ pọn omi kun ikoko wọnni. Nwọn si kún wọn titi de eti. O si wi fun wọn pe, Ẹ bù u jade nisisiyi, ki ẹ si gbé e tọ̀ olori àse lọ. Nwọn si gbé e lọ. Bi olori àse si ti tọ́ omi ti a sọ di waini wò, ti ko si mọ̀ ibi ti o ti wá (ṣugbọn awọn iranṣẹ ti o bù omi na wá mọ̀), olori àse pè ọkọ iyawo, O si wi fun u pe, Olukuluku enia a mã kọ́ gbé waini rere kalẹ; nigbati awọn enia ba si mu yó tan, nigbana ni imu eyi ti kò dara tobẹ̃ wá: ṣugbọn iwọ ti pa waini daradara yi mọ́ titi o fi di isisiyi. Akọṣe iṣẹ àmi yi ni Jesu ṣe ni Kana ti Galili, o si fi ogo rẹ̀ hàn; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbà a gbọ́.
Kà Joh 2
Feti si Joh 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 2:1-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò