Joh 19:17-42

Joh 19:17-42 YBCV

Nitorina nwọn mu Jesu, o si jade lọ, o rù agbelebu fun ara rẹ̀ si ibi ti a npè ni Ibi-agbari, li ede Heberu ti a npè ni Golgota: Nibiti nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn meji miran pẹlu rẹ̀, niha ikini ati nìha keji, Jesu si wà larin. Pilatu si kọ iwe akọle kan pẹlu, o si fi i le ori agbelebu na. Ohun ti a si kọ ni, JESU TI NASARETI ỌBA AWỌN JU. Nitorina ọpọ awọn Ju li o kà iwe akọle yi: nitori ibi ti a gbé kàn Jesu mọ agbelebu sunmọ eti ilu: a si kọ ọ li ède Heberu, ati ti Latini, ati ti Helene. Nitorina awọn olori alufa awọn Ju wi fun Pilatu pe, Máṣe kọ ọ pe, Ọba awọn Ju; ṣugbọn pe on wipe, Emi li Ọba awọn Ju. Pilatu dahùn pe, Ohun ti mo ti kọ tan, mo ti kọ na. Nigbana li awọn ọmọ-ogun, nigbati nwọn kàn Jesu mọ agbelebu tan, nwọn mu aṣọ rẹ̀, nwọn si pín wọn si ipa mẹrin, apakan fun ọmọ-ogun kọkan, ati àwọtẹlẹ rẹ̀: ṣugbọn àwọ̀tẹlẹ na kò li ojuran, nwọn hun u lati oke titi jalẹ. Nitorina nwọn wi fun ara wọn pe, Ẹ má jẹ ki a fà a ya, ṣugbọn ki a ṣẹ kèké nitori rẹ̀, ti ẹniti yio jẹ: ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, ti o wipe, Nwọn pín aṣọ mi larin ara wọn, nwọn si ṣẹ kèké fun aṣọ ileke mi. Nkan wọnyi li awọn ọmọ-ogun ṣe. Iya Jesu ati arabinrin iya rẹ̀ Maria aya Klopa, ati Maria Magdalene, si duro nibi agbelebu. Nitorina nigbati Jesu ri iya rẹ̀, ati ọmọ-ẹhin na duro, ẹniti Jesu fẹràn, o wi fun iya rẹ̀ pe, Obinrin, wò ọmọ rẹ! Lẹhin na li o si wi fun ọmọ-ẹhin na pe, Wò iya rẹ! Lati wakati na lọ li ọmọ-ẹhin na si ti mu u lọ si ile ara rẹ̀. Lẹhin eyi, bi Jesu ti mọ̀ pe, a ti pari ohun gbogbo tan, ki iwe-mimọ́ le ba ṣẹ, o wipe, Orungbẹ ngbẹ mi. A gbé ohun èlo kan kalẹ nibẹ̀ ti o kún fun ọti kikan: nwọn si fi sponge ti o kun fun ọti kikan, sori igi hissopu, nwọn si fi si i li ẹnu. Nitorina nigbati Jesu si ti gbà ọti kikan na, o wipe, O pari: o si tẹ ori rẹ̀ ba, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. Nitori o jẹ ọjọ Ipalẹmọ, ki okú wọn ma bà wà lori agbelebu li ọjọ isimi, (nitori ojọ nla ni ọjọ isimi na) nitorina awọn Ju bẹ̀ Pilatu pe ki a ṣẹ egungun itan wọn, ki a si gbe wọn kuro. Nitorina awọn ọmọ-ogun wá, nwọn si ṣẹ́ egungun itan ti ekini, ati ti ekeji, ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀. Ṣugbọn nigbati nwọn de ọdọ Jesu, ti nwọn si ri pe, o ti kú na, nwọn kò si ṣẹ́ egungun itan rẹ̀: Ṣugbọn ọkan ninu awọn ọmọ-ogun na fi ọ̀kọ gún u li ẹgbẹ, lojukanna ẹ̀jẹ ati omi si tú jade. Ẹniti o ri i si jẹri, otitọ si li ẹrí rẹ̀: o si mọ̀ pe õtọ li on wi, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́. Nkan wọnyi ṣe, ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, ti o wipe, A kì yio fọ́ egungun rẹ̀. Iwe-mimọ́ miran ẹ̀wẹ si wipe, Nwọn o ma wò ẹniti a gún li ọ̀kọ. Lẹhin nkan wọnyi ni Josefu ará Arimatea, ẹniti iṣe ọmọ-ẹhin Jesu, ṣugbọn ni ikọ̀kọ nitori ìbẹru awọn Ju, o bẹ̀ Pilatu ki on ki o le gbé okú Jesu kuro: Pilatu si fun u li aṣẹ. Nitorina li o wá, o si gbé okú Jesu lọ. Nikodemu pẹlu si wá, ẹniti o tọ̀ Jesu wá loru lakọṣe, o si mu àdapọ̀ ojia ati aloe wá, o to ìwọn ọgọrun litra. Bẹni nwọn gbé okú Jesu, nwọn si fi aṣọ ọ̀gbọ dì i pẹlu turari, gẹgẹ bi iṣe awọn Ju ti ri ni isinkú wọn. Agbala kan si wà nibiti a gbé kàn a mọ agbelebu; ibojì titun kan sí wà ninu agbala na, ninu eyiti a ko ti itẹ́ ẹnikẹni si ri. Njẹ nibẹ ni nwọn si tẹ́ Jesu si, nitori Ipalẹmọ́ awọn Ju; nitori ibojì na wà nitosi.