Joh 18:13-40

Joh 18:13-40 YBCV

Nwọn kọ́ fa a lọ sọdọ Anna; nitori on ni iṣe ana Kaiafa, ẹniti iṣe olori alufa li ọdún na. Kaiafa sá ni iṣe, ẹniti o ti ba awọn Ju gbìmọ̀ pe, o ṣanfani ki enia kan kú fun awọn enia. Simoni Peteru si ntọ̀ Jesu lẹhin, ati ọmọ-ẹhin miran kan: ọmọ-ẹhin na jẹ ẹni mimọ̀ fun olori alufa, o si ba Jesu wọ̀ afin olori alufa lọ. Ṣugbọn Peteru duro li ẹnu-ọ̀na lode. Nigbana li ọmọ-ẹhin miran nì, ti iṣe ẹni mimọ̀ fun olori alufa, o jade lọ, o si ba oluṣọna na sọ ọ, o si mu Peteru wọle. Nigbana li ọmọbinrin na ti nṣọ ẹnu-ọ̀na wi fun Peteru pe, Iwọ pẹlu ha ṣe ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin ọkunrin yi bi? O wipe, Emi kọ́. Awọn ọmọ-ọdọ ati awọn onṣẹ si duro nibẹ̀, awọn ẹniti o ti daná ẹyín; nitori otutù mu, nwọn si nyána: Peteru si duro pẹlu wọn, o nyána. Nigbana li olori alufa bi Jesu lẽre niti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati niti ẹkọ́ rẹ̀. Jesu da a lohùn wipe, Emi ti sọ̀rọ ni gbangba fun araiye; nigbagbogbo li emi nkọ́ni ninu sinagogu, ati ni tẹmpili nibiti gbogbo awọn Ju npejọ si: emi kò si sọ ohun kan ni ìkọkọ. Ẽṣe ti iwọ fi mbi mi lẽre? bere lọwọ awọn ti o ti gbọ́ ọ̀rọ mi, ohun ti mo wi fun wọn: wo o, awọn wọnyi mọ̀ ohun ti emi wi. Bi o si ti wi eyi tan, ọkan ninu awọn onṣẹ ti o duro tì i fi ọwọ́ rẹ̀ lù Jesu, wipe, Olori alufa ni iwọ nda lohùn bẹ̃? Jesu da a lohùn wipe, Bi mo ba sọrọ buburu, jẹri si buburu na: ṣugbọn bi rere ba ni, ẽṣe ti iwọ fi nlù mi? Nitori Anna rán a lọ ni didè sọdọ Kaiafa olori alufa. Ṣugbọn Simoni Peteru duro, o si nyána. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iwọ pẹlu ha ṣe ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀? O si sẹ́, o si wipe, Emi kọ́. Ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ olori alufa, ti iṣe ibatan ẹniti Peteru ke etí rẹ̀ sọnù, wipe, Emi kò ha ri ọ pẹlu rẹ̀ li agbala? Nitorina Peteru tún sẹ́: lojukanna akukọ si kọ. Nitorina nwọn fa Jesu lati ọdọ Kaiafa lọ si ibi gbọ̀ngan idajọ: o si jẹ kùtukùtu owurọ̀; awọn tikarawọn kò wọ̀ ini gbọ̀ngàn idajọ, ki nwọn ki o má ṣe di alaimọ́, ṣugbọn ki nwọn ki o le jẹ àse irekọja. Nitorina Pilatu jade tọ̀ wọn lọ, o si wipe, Ẹ̀sun kili ẹnyin mu wá si ọkunrin yi? Nwọn si dahùn wi fun u pe, Ibamaṣepe ọkunrin yi nhùwa ibi, a kì ba ti fà a le ọ lọwọ. Nitorina Pilatu wi fun wọn pe, Ẹ mu u tikaranyin, ki ẹ si ṣe idajọ rẹ̀ gẹgẹ bi ofin nyin. Nitorina li awọn Ju wi fun u pe, Kò tọ́ fun wa lati pa ẹnikẹni: Ki ọ̀rọ Jesu ki o le ba ṣẹ, eyiti o sọ, ti o nṣapẹrẹ irú ikú ti on o kú. Nitorina Pilatu tún wọ̀ inu gbọ̀ngan idajọ lọ, o si pè Jesu, o si wi fun u pe, Ọba awọn Ju ni iwọ iṣe? Jesu dahùn pe, Iwọ sọ eyi fun ara rẹ ni, tabi awọn ẹlomiran sọ ọ fun ọ nitori mi? Pilatu dahùn wipe, Emi iṣe Ju bi? Awọn orilẹ-ède rẹ, ati awọn olori alufa li o fà ọ le emi lọwọ: kini iwọ ṣe? Jesu dahùn wipe, Ijọba mi kì iṣe ti aiye yi: ibaṣepe ijọba mi iṣe ti aiye yi, awọn onṣẹ mi iba jà, ki a má bà fi mi le awọn Ju lọwọ: ṣugbọn nisisiyi ijọba mi kì iṣe lati ihin lọ. Nitorina Pilatu wi fun u pe, Njẹ iwọ ha ṣe ọba bi? Jesu dahùn wipe, Iwọ wipe, ọba li emi iṣe. Nitori eyi li a ṣe bí mi, ati nitori idi eyi ni mo si ṣe wá si aiye, ki emi ki o le jẹri si otitọ. Olukuluku ẹniti iṣe ti otitọ ngbọ́ ohùn mi. Pilatu wi fun u pe, Kili otitọ? Nigbati o si ti wi eyi tan, o tún jade tọ̀ awọn Ju lọ, o si wi fun wọn pe, Emi kò ri ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀. Ṣugbọn ẹnyin ni àṣa kan pe, ki emi ki o da ọkan silẹ fun nyin nigba ajọ irekọja: nitorina ẹ ha fẹ ki emi ki o da Ọba awọn Ju silẹ fun nyin bi? Nitorina gbogbo wọn tún kigbe wipe, Kì iṣe ọkunrin yi, bikoṣe Barabba. Ọlọṣa si ni Barabba.

Video for Joh 18:13-40