Joh 18

18
Àwọn Ọ̀tá Mú Jesu
(Mat 26:47-56; Mak 14:43-50; Luk 22:47-53)
1NIGBATI Jesu si ti sọ nkan wọnyi tan, o jade pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ soke odò Kedroni, nibiti agbala kan wà, ninu eyi ti o wọ̀, on ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
2Judasi, ẹniti o fi i hàn, si mọ̀ ibẹ̀ pẹlu: nitori nigba-pupọ ni Jesu ima lọ sibẹ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
3Nigbana ni Judasi, lẹhin ti o ti gbà ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati awọn onṣẹ́ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn Farisi, wá sibẹ̀ ti awọn ti fitilà ati òguṣọ̀, ati ohun ijà.
4Nitorina bi Jesu ti mọ̀ ohun gbogbo ti mbọ̀ wá ba on, o jade lọ, o si wi fun wọn pe, Tali ẹ nwá?
5Nwọn si da a lohùn wipe, Jesu ti Nasareti. Jesu si wi fun wọn pe, Emi niyi. Ati Judasi pẹlu, ẹniti o fi i hàn, duro pẹlu wọn.
6Nitorina bi o ti wi fun wọn pe, Emi niyi, nwọn bi sẹhin, nwọn si ṣubu lulẹ.
7Nitorina o tún bi wọn lẽre, wipe, Tali ẹ nwá? Nwọn si wipe, Jesu ti Nasareti.
8Jesu dahùn pe, Mo ti wi fun nyin pe, emi niyi: njẹ bi emi li ẹ ba nwá, ẹ jẹ ki awọn wọnyi mã lọ:
9 Ki ọ̀rọ nì ki o le ṣẹ, eyi ti o wipe, Awọn ti iwọ fifun mi, emi kò sọ ọ̀kan nù ninu wọn.
10Nigbana ni Simoni Peteru ẹniti o ni idà, o fà a yọ, o si ṣá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí ọtun rẹ̀ sọnù. Orukọ iranṣẹ na a mã jẹ Malku.
11Nitorina Jesu wi fun Peteru pe, Tẹ̀ idà rẹ bọ inu àkọ rẹ̀: ago ti Baba ti fifun mi, emi ó ṣe alaimu u bi?
Wọ́n mú Jesu lọ siwaju Anna
(Mat 26:57-58; Mak 14:53-54; Luk 22:54)
12Nigbana li ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati olori ẹṣọ́, ati awọn onṣẹ awọn Ju mu Jesu, nwọn si dè e.
13Nwọn kọ́ fa a lọ sọdọ Anna; nitori on ni iṣe ana Kaiafa, ẹniti iṣe olori alufa li ọdún na.
14Kaiafa sá ni iṣe, ẹniti o ti ba awọn Ju gbìmọ̀ pe, o ṣanfani ki enia kan kú fun awọn enia.
Peteru sẹ́ Jesu
(Mat 26:69-70; Mak 14:66-68; Luk 22:55-57)
15Simoni Peteru si ntọ̀ Jesu lẹhin, ati ọmọ-ẹhin miran kan: ọmọ-ẹhin na jẹ ẹni mimọ̀ fun olori alufa, o si ba Jesu wọ̀ afin olori alufa lọ.
16Ṣugbọn Peteru duro li ẹnu-ọ̀na lode. Nigbana li ọmọ-ẹhin miran nì, ti iṣe ẹni mimọ̀ fun olori alufa, o jade lọ, o si ba oluṣọna na sọ ọ, o si mu Peteru wọle.
17Nigbana li ọmọbinrin na ti nṣọ ẹnu-ọ̀na wi fun Peteru pe, Iwọ pẹlu ha ṣe ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin ọkunrin yi bi? O wipe, Emi kọ́.
18Awọn ọmọ-ọdọ ati awọn onṣẹ si duro nibẹ̀, awọn ẹniti o ti daná ẹyín; nitori otutù mu, nwọn si nyána: Peteru si duro pẹlu wọn, o nyána.
Anna Bi Jesu nípa Ẹ̀kọ́ Rẹ̀
(Mat 26:59-66; Mak 14:55-64; Luk 22:66-71)
19Nigbana li olori alufa bi Jesu lẽre niti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati niti ẹkọ́ rẹ̀.
20Jesu da a lohùn wipe, Emi ti sọ̀rọ ni gbangba fun araiye; nigbagbogbo li emi nkọ́ni ninu sinagogu, ati ni tẹmpili nibiti gbogbo awọn Ju npejọ si: emi kò si sọ ohun kan ni ìkọkọ.
21 Ẽṣe ti iwọ fi mbi mi lẽre? bere lọwọ awọn ti o ti gbọ́ ọ̀rọ mi, ohun ti mo wi fun wọn: wo o, awọn wọnyi mọ̀ ohun ti emi wi.
22Bi o si ti wi eyi tan, ọkan ninu awọn onṣẹ ti o duro tì i fi ọwọ́ rẹ̀ lù Jesu, wipe, Olori alufa ni iwọ nda lohùn bẹ̃?
23Jesu da a lohùn wipe, Bi mo ba sọrọ buburu, jẹri si buburu na: ṣugbọn bi rere ba ni, ẽṣe ti iwọ fi nlù mi?
24Nitori Anna rán a lọ ni didè sọdọ Kaiafa olori alufa.
Peteru tún sẹ́ Jesu
(Mat 26:71-75; Mak 14:69-72; Luk 22:58-62)
25Ṣugbọn Simoni Peteru duro, o si nyána. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iwọ pẹlu ha ṣe ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀? O si sẹ́, o si wipe, Emi kọ́.
26Ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ olori alufa, ti iṣe ibatan ẹniti Peteru ke etí rẹ̀ sọnù, wipe, Emi kò ha ri ọ pẹlu rẹ̀ li agbala?
27Nitorina Peteru tún sẹ́: lojukanna akukọ si kọ.
Wọ́n mú Jesu lọ siwaju Pilatu
(Mat 27:1-2,11-14; Mak 15:1-5; Luk 23:1-5)
28Nitorina nwọn fa Jesu lati ọdọ Kaiafa lọ si ibi gbọ̀ngan idajọ: o si jẹ kùtukùtu owurọ̀; awọn tikarawọn kò wọ̀ ini gbọ̀ngàn idajọ, ki nwọn ki o má ṣe di alaimọ́, ṣugbọn ki nwọn ki o le jẹ àse irekọja.
29Nitorina Pilatu jade tọ̀ wọn lọ, o si wipe, Ẹ̀sun kili ẹnyin mu wá si ọkunrin yi?
30Nwọn si dahùn wi fun u pe, Ibamaṣepe ọkunrin yi nhùwa ibi, a kì ba ti fà a le ọ lọwọ.
31Nitorina Pilatu wi fun wọn pe, Ẹ mu u tikaranyin, ki ẹ si ṣe idajọ rẹ̀ gẹgẹ bi ofin nyin. Nitorina li awọn Ju wi fun u pe, Kò tọ́ fun wa lati pa ẹnikẹni:
32Ki ọ̀rọ Jesu ki o le ba ṣẹ, eyiti o sọ, ti o nṣapẹrẹ irú ikú ti on o kú.
33Nitorina Pilatu tún wọ̀ inu gbọ̀ngan idajọ lọ, o si pè Jesu, o si wi fun u pe, Ọba awọn Ju ni iwọ iṣe?
34Jesu dahùn pe, Iwọ sọ eyi fun ara rẹ ni, tabi awọn ẹlomiran sọ ọ fun ọ nitori mi?
35Pilatu dahùn wipe, Emi iṣe Ju bi? Awọn orilẹ-ède rẹ, ati awọn olori alufa li o fà ọ le emi lọwọ: kini iwọ ṣe?
36Jesu dahùn wipe, Ijọba mi kì iṣe ti aiye yi: ibaṣepe ijọba mi iṣe ti aiye yi, awọn onṣẹ mi iba jà, ki a má bà fi mi le awọn Ju lọwọ: ṣugbọn nisisiyi ijọba mi kì iṣe lati ihin lọ.
37Nitorina Pilatu wi fun u pe, Njẹ iwọ ha ṣe ọba bi? Jesu dahùn wipe, Iwọ wipe, ọba li emi iṣe. Nitori eyi li a ṣe bí mi, ati nitori idi eyi ni mo si ṣe wá si aiye, ki emi ki o le jẹri si otitọ. Olukuluku ẹniti iṣe ti otitọ ngbọ́ ohùn mi.
38Pilatu wi fun u pe, Kili otitọ? Nigbati o si ti wi eyi tan, o tún jade tọ̀ awọn Ju lọ, o si wi fun wọn pe, Emi kò ri ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀.
Wọ́n dá Jesu lẹ́bi Ikú
(Mat 27:15-31; Mak 15:6-20; Luk 23:13-25)
39Ṣugbọn ẹnyin ni àṣa kan pe, ki emi ki o da ọkan silẹ fun nyin nigba ajọ irekọja: nitorina ẹ ha fẹ ki emi ki o da Ọba awọn Ju silẹ fun nyin bi?
40Nitorina gbogbo wọn tún kigbe wipe, Kì iṣe ọkunrin yi, bikoṣe Barabba. Ọlọṣa si ni Barabba.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Joh 18: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa