Bi aiye ba korira nyin, ẹ mọ̀ pe, o ti korira mi ṣaju nyin. Ibaṣepe ẹnyin iṣe ti aiye, aiye iba fẹ awọn tirẹ̀; ṣugbọn nitoriti ẹnyin kì iṣe ti aiye, ṣugbọn emi ti yàn nyin kuro ninu aiye, nitori eyi li aiye ṣe korira nyin. Ẹ ranti ọ̀rọ ti mo ti sọ fun nyin pe, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ. Bi nwọn ba ti ṣe inunibini si mi, nwọn ó ṣe inunibini si nyin pẹlu: bi nwọn ba ti pa ọ̀rọ mi mọ́, nwọn ó si pa ti nyin mọ́ pẹlu. Ṣugbọn gbogbo nkan wọnyi ni nwọn o ṣe si nyin, nitori orukọ mi, nitoriti nwọn kò mọ̀ ẹniti o rán mi. Ibaṣepe emi kò ti wá ki n si ti ba wọn sọrọ, nwọn kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi nwọn di alairiwi fun ẹ̀ṣẹ wọn. Ẹniti o ba korira mi, o korira Baba mi pẹlu. Ibaṣepe emi kò ti ṣe iṣẹ wọnni larin wọn, ti ẹlomiran kò ṣe ri, nwọn kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi nwọn ti ri, nwọn si korira ati emi ati Baba mi. Ṣugbọn eyi ṣe ki ọ̀rọ ti a kọ ninu ofin wọn ki o le ṣẹ pe, Nwọn korira mi li ainidi.
Kà Joh 15
Feti si Joh 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 15:18-25
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò