Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹ gbà mi gbọ́ pẹlu. Ninu ile Baba mi ọ̀pọlọpọ ibugbe li o wà: ibamáṣe bẹ̃, emi iba ti sọ fun nyin. Nitori emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin. Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu. Ẹnyin si mọ̀ ibi ti emi gbé nlọ, ẹ si mọ̀ ọ̀na na. Tomasi wi fun u pe, Oluwa, a kò mọ̀ ibiti o gbe nlọ; a o ha ti ṣe mọ̀ ọ̀na na? Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi. Ibaṣepe ẹnyin ti mọ̀ mi, ẹnyin iba ti mọ̀ Baba mi pẹlu: lati isisiyi lọ ẹnyin mọ̀ ọ, ẹ si ti ri i. Filippi wi fun u pe, Oluwa, fi Baba na hàn wa, o si to fun wa. Jesu wi fun u pe, Bi akokò ti mo ba nyin gbé ti pẹ to yi, iwọ kò si ti imọ̀ mi sibẹ̀ Filippi? Ẹniti o ba ti ri mi, o ti ri Baba; iwọ ha ti ṣe wipe, Fi Baba hàn wa?
Kà Joh 14
Feti si Joh 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 14:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò