Joh 12:1-19

Joh 12:1-19 YBCV

NITORINA nigbati ajọ irekọja kù ijọ mẹfa, Jesu wá si Betani, nibiti Lasaru wà, ẹniti o ti kú, ti Jesu ji dide kuro ninu okú. Nwọn si se ase-alẹ fun u nibẹ: Marta si nṣe iranṣẹ: ṣugbọn Lasaru jẹ ọkan ninu awọn ti o joko nibi tabili pẹlu rẹ̀. Nigbana ni Maria mu ororo ikunra nardi, oṣuwọn litra kan, ailabùla, olowo iyebiye, o si nfi kùn Jesu li ẹsẹ, o si nfi irun ori rẹ̀ nù ẹsẹ rẹ̀ nù: ile si kún fun õrùn ikunra na. Nigbana li ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni, ẹniti yio fi i hàn, wipe, Ẽṣe ti a kò tà ororo ikunra yi ni ọ̃durun owo idẹ ki a si fifun awọn talakà? Ṣugbọn o wi eyi, ki iṣe nitoriti o náni awọn talakà; ṣugbọn nitoriti iṣe olè, on li o si ni àpo, a si ma gbé ohun ti a fi sinu rẹ̀. Nigbana ni Jesu wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀, o ṣe e silẹ dè ọjọ sisinku mi. Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin; ṣugbọn emi li ẹ kò ni nigbagbogbo. Nitorina ijọ enia ninu awọn Ju li o mọ̀ pe o wà nibẹ̀: nwọn si wá, kì iṣe nitori Jesu nikan, ṣugbọn ki nwọn le ri Lasaru pẹlu, ẹniti o ti jí dide kuro ninu okú. Ṣugbọn awọn olori alufa gbìmọ ki nwọn le pa Lasaru pẹlu; Nitoripe nipasẹ rẹ̀ li ọ̀pọ ninu awọn Ju jade lọ, nwọn si gbà Jesu gbọ́. Ni ijọ keji nigbati ọ̀pọ enia ti o wá si ajọ gbọ́ pe, Jesu mbọ̀ wá si Jerusalemu, Nwọn mu imọ̀-ọ̀pẹ, nwọn si jade lọ ipade rẹ̀, nwọn si nkigbe pe, Hosanna: Olubukun li ẹniti mbọ̀wá li orukọ Oluwa, Ọba Israeli. Nigbati Jesu si ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan, o gùn u; gẹgẹ bi a ti kọwe pe, Má bẹ̀ru, ọmọbinrin Sioni: wo o, Ọba rẹ mbọ̀ wá, o joko lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ. Nkan wọnyi kò tète yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: ṣugbọn nigbati a ṣe Jesu logo, nigbana ni nwọn ranti pe, a kọwe nkan wọnyi niti rẹ̀, ati pe, on ni nwọn ṣe nkan wọnyi si. Nitorina ijọ enia ti o wà lọdọ rẹ̀, nigbati o pè Lasaru jade ninu iboji rẹ̀, ti o si jí i dide kuro ninu okú, nwọn jẹri. Nitori eyi ni ijọ enia si ṣe lọ ipade rẹ̀, nitoriti nwọn gbọ́ pe o ti ṣe iṣẹ àmi yi. Nitorina awọn Farisi wi fun ara wọn pe, Ẹ kiyesi bi ẹ kò ti le bori li ohunkohun? ẹ wò bi gbogbo aiye ti nwọ́ tọ̀ ọ.

Video for Joh 12:1-19

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joh 12:1-19