Joh 1:35-51

Joh 1:35-51 YBCV

Ni ijọ keji ẹwẹ Johanu duro, ati meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: O si wò Jesu bi o ti nrìn, o si wipe, Wò Ọdọ-agutan Ọlọrun! Awọn ọmọ-ẹhin meji na si gbọ́ nigbati o wi, nwọn si tọ̀ Jesu lẹhin. Nigbana ni Jesu yipada, o ri nwọn ntọ̀ on lẹhin, o si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nwá? Nwọn wi fun u pe, Rabbi, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Olukọni,) nibo ni iwọ ngbé? O wi fun wọn pe, Ẹ wá wò o. Nwọn si wá, nwọn si ri ibi ti o ngbé, nwọn si ba a joko ni ijọ na: nitoriti o jẹ ìwọn wakati kẹwa ọjọ. Ọkan ninu awọn meji ti o gbọ́ ọ̀rọ Johanu, ti o si tọ̀ Jesu lẹhin, ni Anderu, arakunrin Simoni Peteru. On tètekọ ri Simoni arakunrin on tikararẹ̀, o si wi fun u pe, Awa ti ri Messia, itumọ̀ eyi ti ijẹ Kristi. O si mu u wá sọdọ Jesu. Jesu si wò o, o wipe, Iwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa li a o si ma pè ọ, itumọ̀ eyi ti ijẹ Peteru. Ni ọjọ keji Jesu nfẹ jade lọ si Galili, o si ri Filippi, o si wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. Ara Betsaida ni Filippi iṣe, ilu Anderu ati Peteru. Filippi ri Natanaeli, o si wi fun u pe, Awa ti ri ẹniti Mose ninu ofin ati awọn woli ti kọwe rẹ̀, Jesu ti Nasareti, ọmọ Josefu. Natanaeli si wi fun u pe, Ohun rere kan ha le ti Nasareti jade? Filippi wi fun u pe, Wá wò o. Jesu ri Natanaeli mbọ̀ wá sọdọ rẹ̀, o si wi nipa rẹ̀ pe, Wo o, ọmọ Israelì nitõtọ, ninu ẹniti ẹ̀tan kò si! Natanaeli wi fun u pe, Nibo ni iwọ ti mọ̀ mi? Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ki Filippi to pè ọ, nigbati iwọ wà labẹ igi ọ̀pọ́tọ, mo ti ri ọ. Natanaeli dahùn, o si wi fun u pe, Rabbi, iwọ li Ọmọ Ọlọrun; iwọ li Ọba Israeli. Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Nitori mo wi fun ọ pe, mo ri ọ labẹ igi ọpọtọ ni iwọ ṣe gbagbọ? iwọ ó ri ohun ti o pọ̀ju wọnyi lọ. O si wi fun u pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnyin o ri ọrun ṣí silẹ, awọn angẹli Ọlọrun yio si ma gòke, nwọn o si ma sọkalẹ sori Ọmọ-enia.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ