Joh 1:35-42

Joh 1:35-42 YBCV

Ni ijọ keji ẹwẹ Johanu duro, ati meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: O si wò Jesu bi o ti nrìn, o si wipe, Wò Ọdọ-agutan Ọlọrun! Awọn ọmọ-ẹhin meji na si gbọ́ nigbati o wi, nwọn si tọ̀ Jesu lẹhin. Nigbana ni Jesu yipada, o ri nwọn ntọ̀ on lẹhin, o si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nwá? Nwọn wi fun u pe, Rabbi, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Olukọni,) nibo ni iwọ ngbé? O wi fun wọn pe, Ẹ wá wò o. Nwọn si wá, nwọn si ri ibi ti o ngbé, nwọn si ba a joko ni ijọ na: nitoriti o jẹ ìwọn wakati kẹwa ọjọ. Ọkan ninu awọn meji ti o gbọ́ ọ̀rọ Johanu, ti o si tọ̀ Jesu lẹhin, ni Anderu, arakunrin Simoni Peteru. On tètekọ ri Simoni arakunrin on tikararẹ̀, o si wi fun u pe, Awa ti ri Messia, itumọ̀ eyi ti ijẹ Kristi. O si mu u wá sọdọ Jesu. Jesu si wò o, o wipe, Iwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa li a o si ma pè ọ, itumọ̀ eyi ti ijẹ Peteru.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ