Jer 7
7
Jeremiah Waasu ninu Tẹmpili
1Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa wá wipe:
2Duro ni ẹnu ilẹkun ile Oluwa, ki o si kede ọ̀rọ yi wipe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, gbogbo ẹnyin ti Juda ti ẹ wọ̀ ẹnu ilẹkun wọnyi lati sin Oluwa.
3Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, tun ọ̀na ati ìwa nyin ṣe, emi o si jẹ ki ẹnyin ma gbe ibi yi.
4Ẹ máṣe gbẹkẹle ọ̀rọ eke, wipe: Tempili Oluwa, Tempili Oluwa, Tempili Oluwa ni eyi!
5Nitori bi ẹnyin ba tun ọ̀na ati ìwa nyin ṣe nitõtọ; ti ẹnyin ba ṣe idajọ otitọ jalẹ, ẹnikini si ẹnikeji rẹ̀.
6Ti ẹnyin kò ba si ṣẹ́ alejo ni iṣẹ́, alainibaba ati opó, ti ẹnyin kò si ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ ni ibi yi, ti ẹnyin kò si rìn tọ ọlọrun miran si ipalara nyin.
7Nigbana ni emi o mu nyin gbe ibi yi, ni ilẹ ti emi fi fun awọn baba nyin lai ati lailai.
8Sa wò o, ẹnyin gbẹkẹle ọ̀rọ eke, ti kò ni ère.
9Kohaṣepe, ẹnyin njale, ẹ npania, ẹ nṣe panṣaga, ẹ nbura eke, ẹ nsun turari fun Baali, ẹ si nrin tọ ọlọrun miran ti ẹnyin kò mọ̀?
10Ẹnyin si wá, ẹ si duro niwaju mi ni ile yi, ti a fi orukọ mi pè! ẹnyin si wipe: Gbà wa, lati ṣe gbogbo irira wọnyi?
11Ile yi, ti ẹ fi orukọ mi pè, o ha di iho olè li oju nyin? sa wò o, emi tikarami ti ri i, li Oluwa wi.
12Ẹ si lọ nisisiyi, si ibujoko mi, ti o wà ni Ṣilo, ni ibi ti emi fi orukọ mi si li àtetekọṣe, ki ẹ si ri ohun ti emi ṣe si i nitori ìwa-buburu enia mi, Israeli.
13Njẹ nisisiyi, nitori ẹnyin ti ṣe gbogbo iṣẹ wọnyi, li Oluwa wi, ti emi si ba nyin sọ̀rọ, ti emi ndide ni kutukutu ti mo si nsọ, ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́; ti emi si npè nyin, ṣugbọn ẹnyin kò dahùn.
14Nitorina li emi o ṣe si ile yi, ti a pè ni orukọ mi, ti ẹ gbẹkẹle, ati si ibi ti emi fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin, gẹgẹ bi emi ti ṣe si Ṣilo.
15Emi o si ṣá nyin tì kuro niwaju mi, gẹgẹ bi mo ti ṣá awọn arakunrin nyin tì, ani gbogbo iru-ọmọ Efraimu.
Àìgbọràn Àwọn Eniyan Náà
16Nitorina máṣe gbadura fun enia yi, bẹ̃ni ki o má si gbe igbe rẹ soke ati adura fun wọn, bẹ̃ni ki o má ṣe rọ̀ mi: nitori emi kì yio gbọ́ tirẹ.
17Iwọ kò ha ri ohun ti nwọn nṣe ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu?
18Awọn ọmọ ko igi jọ, awọn baba nda iná, awọn obinrin npò akara lati ṣe akara didùn fun ayaba-ọrun ati lati tú ẹbọ-ọrẹ mimu jade fun ọlọrun miran, ki nwọn ki o le rú ibinu mi soke.
19Ibinu mi ni nwọn ha ru soke bi? li Oluwa wi, kì ha ṣe si ara wọn fun rudurudu oju wọn?
20Nitorina bayi li Ọlọrun Oluwa wi, sa wò o, a o dà ibinu ati irunu mi si ibi yi, sori enia ati sori ẹranko, ati sori igi igbo, ati sori eso ilẹ, yio si jo, a kì o le pa iná rẹ̀.
21Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, kó ẹbọ sisun nyin pẹlu ẹbọ jijẹ nyin, ki ẹ si jẹ ẹran.
22Nitori emi kò wi fun awọn baba nyin, bẹ̃ni emi kò paṣẹ fun wọn ni ọjọ ti mo mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti niti ẹbọ sisun tabi ẹbọ jijẹ:
23Ṣugbọn eyi ni mo paṣẹ fun wọn wipe, Gba ohùn mi gbọ́, emi o si jẹ Ọlọrun nyin, ẹnyin o si jẹ enia mi: ki ẹ si rin ni gbogbo ọ̀na ti mo ti paṣẹ fun nyin, ki o le dara fun nyin.
24Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò tẹ eti silẹ, nwọn si rin ni ìmọ ati agidi ọkàn buburu wọn, nwọn si kọ̀ ẹ̀hin wọn kì iṣe oju wọn si mi.
25Lati ọjọ ti baba nyin ti ti ilẹ Egipti jade wá titi di oni, emi ti rán gbogbo iranṣẹ mi, awọn woli si nyin, lojojumọ emi dide ni kutukutu, emi si rán wọn.
26Sibẹ nwọn kò gbọ́ temi, bẹ̃ni nwọn kò tẹti wọn silẹ, sugbọn nwọn mu ọrun le, nwọn ṣe buburu jù awọn baba wọn lọ.
27Bi iwọ ba si wi gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun wọn, nwọn kì yio gbọ́ tirẹ: iwọ o si pè wọn, ṣugbọn nwọn kì o da ọ lohùn.
28Iwọ o si wi fun wọn pe: Eyi ni enia na ti kò gba ohùn Oluwa Ọlọrun rẹ̀ gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò gba ẹkọ́: otitọ ṣègbe, a si ke e kuro li ẹnu wọn.
Ìwà Ẹ̀ṣẹ̀ ní Àfonífojì Hinomu
29Fá irun ori rẹ, ki o si sọ ọ nù, ki o si sọkun lori oke: nitori Oluwa ti kọ̀ iran ibinu rẹ̀ silẹ, o si ṣa wọn tì.
30Nitori awọn ọmọ Juda ti ṣe buburu niwaju mi, li Oluwa wi; nwọn ti gbe ohun irira wọn kalẹ sinu ile ti a pe li orukọ mi, lati ba a jẹ.
31Nwọn si ti kọ́ ibi giga Tofeti, ti o wà ni afonifoji ọmọ Hinnomu, lati sun awọn ọmọkunrin ati awọn ọmọbinrin wọn ninu iná; aṣẹ eyiti emi kò pa fun wọn, bẹ̃ni kò si wá si inu mi.
32Nitorina sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti a kì o pe e ni Tofeti mọ, tabi afonifoji ọmọ Hinnomu, ṣugbọn a o pe e ni afonifoji ipakupa: nitori nwọn o sin oku ni Tofeti, titi àye kì yio si mọ.
33Okú awọn enia yi yio di onjẹ fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ẹranko ilẹ: ẹnikan kì yio lé wọn kuro.
34Emi o si mu ki ohùn inu-didun ki o da kuro ni ilu Juda ati kuro ni ita Jerusalemu, ohùn ayọ̀, ohùn ọkọ iyawo, ati ti iyawo; nitori ilẹ na yio di ahoro.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 7: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.